Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú I. Joh 1:8

Àwọn Ìṣé Ìrònúpìwàdà
Ojọ́ Márùn-ún
Ìrònúpìwàdà jẹ́ ọ̀kan lára ìgbésẹ̀ tó ṣe kókó tí à ń gbé láti mọ Krístì ní Olùgbàlà wa. Ìrònúpìwàdà ni ojúṣe wa, Ìdáríjì sì ni èsì Ọlọ́run sí wa láti inú ìfẹ́ pípé tí ó ní sí wa. Lásìkò ètò ọlọ́jọ́ márùún yìí, wàá gba bíbélì kíkà ojojúmọ́ àti àmúlò ní ṣókí tí a gbékalẹ̀ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní òye síi nípa ìwúlò Ìrònúpìwàdà nínú ìrìn wa pẹ̀lú Krístì. Fún àwọn ètò míràn, ṣe àyẹ̀wò www.finds.life.church

Àwon Òtá Okàn
Ọjọ marun
Gẹ́gẹ́ bíi ọkàn tí ara to méwulọ́wọ́ lè pa ara wa run, ọkàn tọ́ méwulọ́wọ́ nípa tí èrò - ìmọ̀lára àti nípa tẹ́mí lè pá ìwọ àti àwọn àjọṣe rè run. Fún ọjọ́ márùn-ún tó ń mbò, jẹ́ kí Andy Stanley rán ẹ lọ́wọ́ láti wò inú ara rè fún àwọn ọ̀tá ọkàn mẹ́rin tó wọ́pọ̀ — èbi, ìbínú, ojúkòkòrò, àti owú — àti pé kò ẹ bí ó máa ṣe yọ wón kúrò.

Ṣé Mo Lè B'orí Ẹ̀ṣẹ̀ àtí Ìdánwò Nítòótọ́?
Ọjọ marun
Ǹjẹ́ o ti bi ara rẹ léèrè rí pé, "Kílódé tí mo ṣì ńbá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn já ìjàkadì?" Àpóstélì Pọ́ọ́lù pàápàá sọ bẹ́ẹ̀ ní Róòmù 7:15: "Kìí ṣe ohun tí mo fẹ́ ni èmi ńṣe, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìra ni èmi ńṣe." Báwo ni a ṣe lè dá ẹ̀ṣẹ̀ l'ọ́wọ́ kọ́ kí ó má baà p'agi dínà ìgbé-ayé ẹ̀mí wa? Ṣé èyí tilẹ̀ ṣeéṣe? Jẹ́ kí á jíròrò lórí ẹ̀ṣẹ̀, ìdanwò, Èṣù, àti, ìfẹ́ Ọlọ́run.