Gẹn 17
17
Ilà Abẹ́ Kíkọ, Àmì Majẹmu Ọlọrun
1NIGBATI Abramu si di ẹni ọkandilọgọrun ọdún, OLUWA farahàn Abramu, o si wi fun u pe, Emi li Ọlọrun Olodumare; mã rìn niwaju mi, ki iwọ ki o si pé.
2Emi o si ba ọ dá majẹmu mi, emi o si sọ ọ di pupọ̀ gidigidi.
3Abramu si dojubolẹ; Ọlọrun si ba a sọ̀rọ pe,
4Bi o ṣe ti emi ni, kiyesi i, majẹmu mi wà pẹlu rẹ, iwọ o si ṣe baba orilẹ-ède pupọ̀.
5Bẹ̃li a ki yio si pe orukọ rẹ ni Abramu mọ́, bikoṣe Abrahamu li orukọ rẹ yio jẹ; nitoriti mo ti sọ ọ di baba orilẹ-ède pupọ̀.
6Emi o si mu ọ bí si i pupọpupọ, ọ̀pọ orilẹ-ède li emi o si mu ti ọdọ rẹ wá, ati awọn ọba ni yio ti inu rẹ jade wá.
7Emi o si gbe majẹmu mi kalẹ lãrin temi tirẹ, ati lãrin irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn, ni majẹmu aiyeraiye, lati ma ṣe Ọlọrun rẹ, ati ti irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ.
8Emi o si fi ilẹ ti iwọ ṣe alejo nibẹ̀ fun ọ, ati fun irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ, gbogbo ilẹ Kenaani ni iní titi lailai; emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn.
9Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Nitorina ki iwọ ki o ma pa majẹmu mi mọ́, iwọ, ati irú-ọmọ rẹ lẹhin rẹ ni iran-iran wọn.
10Eyi ni majẹmu mi, ti ẹnyin o ma pamọ́ lãrin temi ti nyin, ati lãrin irú-ọmọ rẹ, lẹhin rẹ; gbogbo ọmọkunrin inu nyin li a o kọ ni ilà.
11Ẹnyin o si kọ ara nyin ni ilà; on ni yio si ṣe àmi majẹmu lãrin temi ti nyin.
12Ẹniti o ba si di ọmọkunrin ijọ mẹjọ ninu nyin li a o kọ ni ilà, gbogbo ọmọkunrin ni iran-iran nyin, ati ẹniti a bí ni ile, tabi ti a fi owo rà lọwọ alejo, ti ki iṣe irú-ọmọ rẹ.
13Ẹniti a bí ni ile rẹ, ati ẹniti a fi owo rẹ rà, a kò le ṣe alaikọ ọ ni ilà: bẹ̃ni majẹmu mi yio si wà li ara nyin ni majẹmu aiyeraiye.
14Ati ọmọkunrin alaikọlà ti a kò kọ ni ilà ara rẹ̀, ọkàn na li a o si ké kuro ninu awọn enia rẹ̀, o dà majẹmu mi.
15Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Bi o ṣe ti Sarai, aya rẹ nì, iwọ ki yio pè orukọ rẹ̀ ni Sarai mọ́, bikoṣe Sara li orukọ rẹ̀ yio ma jẹ.
16Emi o si busi i fun u, emi o si bùn ọ li ọmọkunrin kan pẹlu lati ọdọ rẹ̀ wá, bẹ̃li emi o si busi i fun u, on o si ṣe iya ọ̀pọ orilẹ-ède; awọn ọba enia ni yio ti ọdọ rẹ̀ wá.
17Nigbana li Abrahamu dojubolẹ, o si rẹrin, o si wi li ọkàn rẹ̀ pe, A o ha bímọ fun ẹni ọgọrun ọdún? Sara ti iṣe ẹni ãdọrun ọdún yio ha bímọ bi?
18Abrahamu si wi fun Ọlọrun pe, Ki Iṣmaeli ki o wà lãye niwaju rẹ!
19Ọlọrun si wipe, Sara, aya rẹ, yio bí ọmọkunrin kan fun ọ nitõtọ; iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Isaaki: emi o fi idi majẹmu mi mulẹ pẹlu rẹ̀, ni majẹmu aiyeraiye, ati pẹlu irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.
20Emi si ti gbọ́ adura rẹ fun Iṣmaeli: kiyesi i, emi o si busi i fun u, emi o si mu u bisi i, emi o si sọ ọ di pupọ̀ gidigidi; ijoye mejila ni on o bí, emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla:
21Ṣugbọn majẹmu mi li emi o ba Isaaki dá, ẹniti Sara yio bí fun ọ li akoko iwoyi amọ́dun.
22O si fi i silẹ li ọ̀rọ iba a sọ, Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ Abrahamu.
23Abrahamu si mu Iṣmaeli, ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo awọn ọmọ-ọdọ ọkunrin ti a bí ni ile rẹ̀, ati gbogbo awọn ti a fi owo rẹ̀ rà, gbogbo ẹniti iṣe ọkunrin ninu awọn enia ile Abrahamu; o si kọ wọn ni ilà ara li ọjọ́ na gan, bi Ọlọrun ti sọ fun u.
24Abrahamu si jẹ ẹni ọkandilọgọrun ọdún, nigbati a kọ ọ ni ilà ara rẹ̀.
25Ati Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkunrin jẹ ẹni ọdún mẹtala nigbati a kọ ọ ni ilà ara rẹ̀.
26Li ọjọ́ na gan li a kọ Abrahamu ni ilà, ati Iṣmaeli ọmọ rẹ̀ ọkunrin.
27Ati gbogbo awọn ọkunrin ile rẹ̀, ti a bi ninu ile rẹ̀, ati ti a si fi owo rà lọwọ alejò, ni a kọ ni ilà pẹlu rẹ̀.
Pilihan Saat Ini:
Gẹn 17: YBCV
Sorotan
Berbagi
Salin
Ingin menyimpan sorotan di semua perangkat Anda? Daftar atau masuk
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.