Gẹn 16
16
Hagari ati Iṣimaeli
1SARAI, aya Abramu, kò bímọ fun u: ṣugbọn o li ọmọ-ọdọ kan obinrin, ara Egipti, orukọ ẹniti ijẹ Hagari.
2Sarai si wi fun Abramu pe, kiyesi i na, OLUWA dá mi duro lati bímọ: emi bẹ̀ ọ, wọle tọ̀ ọmọbinrin ọdọ mi; o le ṣepe bọya emi a ti ipasẹ rẹ̀ li ọmọ. Abramu si gbà ohùn Sarai gbọ́.
3Sarai, aya Abramu, si mu Hagari ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ ara Egipti na, lẹhin igbati Abramu gbé ilẹ Kenaani li ọdún mẹwa, o si fi i fun Abramu ọkọ rẹ̀ lati ma ṣe aya rẹ̀.
4On si wọle tọ̀ Hagari, o si loyun: nigbati o ri pe on loyun, oluwa rẹ̀ obinrin wa di ẹ̀gan li oju rẹ̀.
5Sarai si wi fun Abramu pe, Ẹbi mi wà lori rẹ: emi li o fi ọmọbinrin ọdọ mi fun ọ li àiya; nigbati o si ri pe on loyun, mo di ẹ̀gan li oju rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe idajọ lãrin temi tirẹ.
6Ṣugbọn Abramu wi fun Sarai pe, Wò o, ọmọbinrin ọdọ rẹ wà li ọwọ́ rẹ: fi i ṣe bi o ti tọ́ li oju rẹ. Nigbati Sarai nfõró rẹ̀, o sá lọ kuro lọdọ rẹ̀.
7Angeli OLUWA si ri i li ẹba isun omi ni ijù, li ẹba isun omi li ọ̀na Ṣuri.
8O si wipe, Hagari ọmọbinrin ọdọ Sarai, nibo ni iwọ ti mbọ̀? nibo ni iwọ si nrè? O si wipe, emi sá kuro niwaju Sarai oluwa mi.
9Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Pada, lọ si ọdọ oluwa rẹ, ki o si tẹriba fun u.
10Angeli OLUWA na si wi fun u pe, Ni bíbi emi o mu iru-ọmọ rẹ bísi i, a ki yio si le kà wọn fun ọ̀pọlọpọ.
11Angeli OLUWA na si wi fun u pe, kiyesi i iwọ loyun, iwọ o si bí ọmọkunrin, iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Iṣmaeli; nitoriti OLUWA ti gbọ́ ohùn arò rẹ.
12Jagidijagan enia ni yio si ṣe; ọwọ́ rẹ̀ yio wà lara enia gbogbo, ọwọ́ enia gbogbo yio si wà lara rẹ̀: on o si ma gbé iwaju gbogbo awọn arakunrin rẹ̀.
13O si pè orukọ OLUWA ti o ba a sọ̀rọ ni, Iwọ Ọlọrun ti o ri mi: nitori ti o wipe, Emi ha wá ẹniti o ri mi kiri nihin?
14Nitori na li a ṣe npè kanga na ni Beer-lahai-roi: kiyesi i, o wà li agbedemeji Kadeṣi on Beredi.
15Hagari si bí ọmọkunrin kan fun Abramu: Abramu si pè orukọ ọmọ ti Hagari bí ni Iṣmaeli.
16Abramu si jẹ ẹni ẹrindilãdọrun ọdún, nigbati Hagari bí Iṣmaeli fun Abramu.
Pilihan Saat Ini:
Gẹn 16: YBCV
Sorotan
Berbagi
Salin
Ingin menyimpan sorotan di semua perangkat Anda? Daftar atau masuk
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.