Johanu Ìfáàrà
Ìfáàrà
A kọ ìwé ìhìnrere Jesu láti ọwọ́ Johanu lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí Jesu kú tí ó sì jí dìde láti ọwọ́ aposteli Johanu fún ète pàtàkì pé, gbogbo ẹni tó bá kà á yóò gbàgbọ́ nínú Kristi, yóò ní ìyè láti ipasẹ̀ orúkọ rẹ̀ (20.31). Ìwé ìhìnrere Johanu bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣáájú tí kò lẹ́gbẹ́. Ó fi Jesu hàn nínú ìhìnrere yìí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣáájú àkókò tí a bí I. Ó ṣàpèjúwe àwọn iṣẹ́ ìyanu àti ìkọ́ni rẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ju èyí tí àwọn aṣíwájú ti sọ nípa rẹ̀ lọ. Ó fi ààyè tí ó gbòòrò sílẹ̀ (14.17) láti fi ṣe àpèjúwe bí Jesu ṣe kọ́ àwọn aposteli kí ó tó kú lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jesu, ó fi ààyè kan jí ìfarahàn Jesu sí àwọn aposteli.
Ìwé Ìyìn rere Johanu ṣe àtẹnumọ́ ìyè àìnípẹ̀kun nínú Kristi àti ìtumọ̀ ìgbé ayé rẹ̀ ju àwọn ìwé ìhìnrere tókù lọ. Johanu fi ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tọ́ka sí àwọn nǹkan ti ẹ̀mí bí i ìmọ́lẹ̀ òtítọ́, ìfẹ́, olùṣọ́-àgùntàn rere, ẹnu-ọ̀nà, àjíǹde àti ìyè, oúnjẹ ìyè àti ọ̀pọ̀ mìíràn. Àwọn nǹkan iyebíye tí a rí ní 14-17 fi ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ Jesu sí onígbàgbọ́ àti àlàáfíà tó ń wá láti inú ìgbẹ́kẹ̀lé Kristi hàn.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ọ̀rọ̀ ìṣáájú tó fi Jesu hàn bí ìyè àìnípẹ̀kun 1.1-14.
ii. Iṣẹ́ ìta gbangba ṣáájú ti Galili 1.15–4.54.
iii. Iṣẹ́ ìta gbangba Jesu ní Galili àti ìwàyáàjà ní Jerusalẹmu 5.1–10.42.
iv. Jíjí Lasaru dìde kúrò ní ipò òkú 11.1-57.
v. Ìparí iṣẹ́ ìta gbangba Jesu 12.1–13.38.
vi. Ìkọ́ni tí Jesu ṣe gbẹ̀yìn 14.1–17.26.
vii. Ikú àti àjíǹde Jesu 18.1–20.18.
viii. Àjíǹde àti ìfarahàn Jesu 20.11–21.25.
હાલમાં પસંદ કરેલ:
Johanu Ìfáàrà: YCB
Highlight
શેર કરો
નકલ કરો
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.