Johanu 1
1
Ọ̀rọ̀ di ẹran-ara
1 Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà. 2Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe. 3 Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá. 4 Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé, 5 ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì borí rẹ̀.
6 Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Johanu. 7Òun ni a sì rán fún ẹ̀rí, kí ó lè ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo ènìyàn kí ó lè gbàgbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀. 8Òun fúnrarẹ̀ kì í ṣe ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an wá láti ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà.
9 Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé. 10Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n. 11Ó tọ àwọn tirẹ̀ wá, àwọn tirẹ̀ kò sì gbà á. 12 Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àní àwọn náà tí ó gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́, àwọn ni ó fi ẹ̀tọ́ fún láti di ọmọ Ọlọ́run; 13 Àwọn ọmọ tí kì í ṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run.
14 Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo ọmọ rẹ kan ṣoṣo, tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.
15 Johanu sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ” 16 Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún. 17 Nítorí pé nípasẹ̀ Mose ni a ti fi òfin fún ni ṣùgbọ́n òun; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ láti ipasẹ̀ Jesu Kristi wá. 18 Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọ́run rí, bí kò ṣe òun nìkan, àní ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ẹni tí òun pàápàá jẹ́ Ọlọ́run, tí ó sì wà ní ìbásepọ̀ tí ó súnmọ́ jùlọ pẹ̀lú baba, òun náà ni ó sì fi í hàn.
Johanu sọ pé òun kì í ṣe Kristi
19 Èyí sì ni ẹ̀rí Johanu, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi láti Jerusalẹmu wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe. 20 Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, “Èmi kì í ṣe Kristi náà.”
21 Wọ́n sì bi í léèrè pé, “Ta ha ni ìwọ? Elijah ni ìwọ bí?”
Ó sì wí pé, “Èmi kọ́.”
“Ìwọ ni wòlíì náà bí?”
Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”
22Ní ìparí wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ í ṣe? Fún wa ní ìdáhùn kí àwa kí ó lè mú èsì padà tọ àwọn tí ó rán wa wá lọ. Kí ni ìwọ wí nípa ti ara rẹ?”
23 Johanu sì fi ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah fún wọn ní èsì pé, “Èmi ni ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà Olúwa ní títọ́.’ ”
24Ọ̀kan nínú àwọn Farisi tí a rán 25bi í léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń bamitiisi nígbà náà, bí ìwọ kì í bá ṣe Kristi, tàbí Elijah, tàbí wòlíì náà?”
26 Johanu dá wọn lóhùn, wí pé, “Èmi ń fi omi bamitiisi: ẹnìkan dúró láàrín yín, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀; 27Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”
28Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Betani ní òdìkejì odò Jordani, níbi tí Johanu ti ń fi omi bamitiisi.
Jesu jẹ́ Ọ̀dọ́-Àgùntàn Ọlọ́run
29 Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! 30Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi, tí ó pọ̀jù mí lọ, nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’ 31Èmi gan an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Israẹli.”
32 Nígbà náà ni Johanu jẹ́rìí sí i pé: “Mo rí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e. 33Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitiisi sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi.’ 34Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu àkọ́kọ́
35 Ní ọjọ́ kejì, Johanu dúró pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 36Nígbà tí ó sì rí Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!”
37Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì gbọ́ ohun tí ó wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì í tọ Jesu lẹ́yìn. 38Nígbà náà ni Jesu yípadà, ó rí i pé wọ́n ń tọ òun lẹ́yìn, ó sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin ń wá?”
Wọ́n wí fún un pé, “Rabbi” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe Olùkọ́ni), “Níbo ni ìwọ ń gbé?”
39Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.”
Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.
40 Anderu arákùnrin Simoni Peteru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó sì tọ Jesu lẹ́yìn. 41 Ohun àkọ́kọ́ tí Anderu ṣe ni láti wá Simoni arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Messia” (ẹni tí ṣe Kristi). 42 Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu.
Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).
Jesu pe Filipi àti Natanaeli
43 Ní ọjọ́ kejì Jesu ń fẹ́ jáde lọ sí Galili, ó sì rí Filipi, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
44Filipi gẹ́gẹ́ bí i Anderu àti Peteru, jẹ́ ará ìlú Betisaida. 45 Filipi rí Natanaeli, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni náà tí Mose kọ nípa rẹ̀ nínú òfin àti ẹni tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé rẹ̀—Jesu ti Nasareti, ọmọ Josẹfu.”
46 Natanaeli béèrè pé, “Nasareti? Ohun rere kan ha lè ti ibẹ̀ jáde?”
Filipi wí fún un pé, “Wá wò ó.”
47Jesu rí Natanaeli ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí nípa rẹ̀ pé, “Èyí ni ọmọ Israẹli tòótọ́, nínú ẹni tí ẹ̀tàn kò sí.”
48Natanaeli béèrè pé, “Báwo ni ìwọ ti ṣe mọ̀ mí?”
Jesu sì dáhùn pé, “Èmi rí ọ nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ kí Filipi tó pè ọ́.”
49 Nígbà náà ni Natanaeli sọ ọ́ gbangba pé, “Rabbi, ìwọ ni ọmọ Ọlọ́run; Ìwọ ni ọba Israẹli.”
50Jesu sì wí fún un pé, “Ìwọ gbàgbọ́ nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́. Ìwọ ó rí ohun tí ó pọ̀jù ìwọ̀nyí lọ.” 51 Nígbà náà ni ó fi kún un pé, “Èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹ̀yin yóò rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, àwọn angẹli Ọlọ́run yóò sì máa gòkè, wọ́n ó sì máa sọ̀kalẹ̀ sórí Ọmọ Ènìyàn.”
હાલમાં પસંદ કરેલ:
Johanu 1: YCB
Highlight
શેર કરો
નકલ કરો
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.