YouVersion Logo
Search Icon

Job 28

28
1NITOTỌ ipa-ilẹ fàdaka mbẹ, ati ibi ti nwọn a ma idà wura.
2Ninu ilẹ li a gbe nwà irin, bàba li a si ndà lati inu okuta wá.
3Enia li o pari òkunkun, o si ṣe awari okuta òkunkun ati ti inu ojiji ikú si iha gbogbo.
4Nwọn wá iho ilẹ ti o jìn si awọn ti o ngbe oke, awọn ti ẹsẹ enia gbagbe nwọn rọ si isalẹ, nwọn rọ si isalẹ jina si awọn enia.
5Bi o ṣe ti ilẹ ni, ninu rẹ̀ ni onjẹ ti ijade wá, ati ohun ti o wà nisalẹ li o yi soke bi ẹnipe iná.
6Okuta ibẹ ni ibi okuta Safiri, o si ni erupẹ wura.
7Ipa ọ̀na na ni ẹiyẹ kò mọ̀, ati oju gunugun kò ri i ri.
8Awọn ọmọ kiniun kò rin ibẹ rí, bẹ̃ni kiniun ti nké ramuramu kò kọja nibẹ rí.
9O fi ọwọ rẹ̀ le akọ apata, o yi oke-nla po lati idi rẹ̀ wá.
10O si la ipa-odò ṣiṣàn ninu apata, oju rẹ̀ si ri ohun iyebiye gbogbo.
11O si sé iṣàn odò ki o má ṣe kún akunya, o si mu ohun ti o lumọ hàn jade wá si imọlẹ.
12Ṣugbọn nibo li a o gbe wá ọgbọ́n ri, nibo si ni ibi oye?
13Enia kò mọ̀ iye rẹ̀, bẹ̃li a kò le iri i ni ilẹ awọn alãyè.
14Ọgbun wipe, kò si ninu mi, omi-okun si wipe, kò si ninu mi.
15A kò le fi wura rà a, bẹ̃li a kò le ifi òṣuwọn wọ̀n fadaka ni iye rẹ̀.
16A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri.
17Wura ati okuta kristali kò to ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rẹ̀.
18A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọ́n si jù okuta rubi lọ.
19Okuta topasi ti Etiopia kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le ifi wura daradara diye le e.
20Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye?
21A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun.
22Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀.
23Ọlọrun li o moye ipa ọ̀na rẹ̀, o si mọ̀ ipo rẹ̀,
24Nitoripe o woye de opin aiye, o si ri gbogbo isalẹ ọrun.
25Lati dà òṣuwọn fun afẹfẹ, o si fi òṣuwọn wọ̀n omiyomi.
26Nigbati o paṣẹ fun òjo, ti o si la ọ̀na fun mànamana ãrá:
27Nigbana li o ri i, o si sọ ọ jade, o pèse rẹ̀ silẹ, ani o si wadi rẹ̀ ri.
28Ati fun enia li o wipe, kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọ́n, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye!

Currently Selected:

Job 28: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in