YouVersion Logo
Search Icon

Job 27

27
1PẸLUPẸLU Jobu si tun sọ kún ọ̀rọ owe rẹ̀ o si wipe,
2Bi Ọlọrun ti mbẹ ẹniti o gba idajọ mi lọ, ati Olodumare ti o bà mi li ọkàn jẹ.
3Niwọn igba ti ẹmi mi mbẹ ninu mi, ati ti ẹmi Ọlọrun mbẹ ni iho imú mi.
4Ete mi kì yio sọ̀rọ eké, bẹ̃li ahọn mi kì yio sọ̀rọ ẹ̀tan.
5Ki a ma ri pe emi ndá nyin li are, titi emi o fi kú emi kì yio ṣi ìwa otitọ mi kuro lọdọ mi.
6Ododo mi li emi dimú ṣinṣin, emi kì yio si jọwọ rẹ̀ lọwọ; aiya mi kì yio si gan ọjọ kan ninu ọjọ aiye mi.
7Ki ọta mi ki o dàbi enia buburu, ati ẹniti ndide si mi ki o dàbi ẹni alaiṣododo.
8Nitoripe kini ireti àgabagebe, nigbati Ọlọrun ba ke ẹmi rẹ̀ kuro, nigbati o si fà a jade.
9Ọlọrun yio ha gbọ́ adura rẹ̀, nigbati ipọnju ba de si i?
10On ha le ni inu-didùn si Olodumare, on ha le ma kepe Ọlọrun nigbagbogbo?
11Emi o kọ́ nyin li ẹkọ́ niti ọwọ Ọlọrun: eyi ti mbẹ lọdọ Olodumare li emi kì yio fi pamọ.
12Kiyesi i, gbogbo nyin li o ti ri i, nitori kili ẹnyin ṣe jasi asan pọ̀ bẹ̃?
13Eyi ni ipín enia buburu lọdọ Ọlọrun, ati ogún awọn aninilara, ti nwọn o gbà lọwọ Olodumare.
14Bi awọn ọmọ rẹ̀ ba di pupọ̀, fun idà ni, awọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ kì yio yo fun onjẹ.
15Awọn ti o kù ninu tirẹ̀ li a o sinkú ninu ajakalẹ àrun: awọn opó rẹ̀ kì yio si sọkún.
16Bi o tilẹ kó fàdaka jọ bi erupẹ, ti o si da aṣọ jọ bi amọ̀.
17Ki o ma dá a, ṣugbọn awọn olõtọ ni yio lò o; awọn alaiṣẹ̀ ni yio si pin fadaka na.
18On kọ́ ile rẹ̀ bi kòkoro aṣọ, ati bi agọbukà ti oluṣọ pa.
19Ọlọrọ̀ yio dubulẹ, ṣugbọn on kì o tùn ṣe bẹ̃ mọ́, o ṣiju rẹ̀, on kò sì si.
20Ẹ̀ru nla bà a bi omi ṣiṣan, ẹ̀fufu nla ji i gbe lọ li oru.
21Ẹfufu ila-õrùn gbe e lọ, on si lọ; ati bi iji nla o si fà a kuro ni ipo rẹ̀.
22Nitoripe Olodumare yio kọlù u, kì o sì dasi; on iba yọ̀ lati sá kuro li ọwọ rẹ̀.
23Awọn enia yio si ṣapẹ si i lori, nwọn o si ṣe ṣiọ si i kuro ni ipò rẹ̀.

Currently Selected:

Job 27: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in