YouVersion Logo
Search Icon

Job 29

29
Ìparí Ọ̀rọ̀ Jobu
1PẸLUPẸLU Jobu si tun gbẹnu le ọ̀rọ rẹ̀ o si wipe,
2A! ibaṣepe emi wà bi igba oṣu ti o kọja, bi ọjọ ti Ọlọrun pa mi mọ́!
3Nigbati fitila rẹ̀ tàn si mi li ori, ati nipa imọlẹ rẹ̀ emi rìn ninu òkunkun ja.
4Bi mo ti ri nigba ọ̀dọ́ mi, nigbati aṣiri Ọlọrun wà ninu agọ mi.
5Nigbati Olodumare wà sibẹ pẹlu mi, nigbati awọn ọmọ mi wà yi mi ka.
6Nigbati emi nfi ori-amọ wẹ̀ iṣisẹ mi, ati ti apata ntú iṣàn ororo jade fun mi wá.
7Nigbati mo jade là arin ilu lọ si ẹnu ibode, nigbati mo tẹ ìtẹ mi ni igboro.
8Nigbana ni awọn ọdọmọkunrin ri mi, nwọn si sapamọ́, awọn àgba dide duro.
9Awọn ọmọ-alade dakẹ ọ̀rọ sisọ, nwọn a si fi ọwọ wọn le ẹnu.
10Awọn ọlọla dakẹ, ahọn wọn si lẹmọ èrigi ẹnu wọn.
11Nitoripe eti gbọ́ ti emi, a si sure fun mi, oju si ri mi, on a jẹri mi.
12Nitoriti mo gba talaka ti nsọkun, ati alainibaba, ati alaini oluranlọwọ.
13Isure ẹniti o fẹrẹ iṣegbe wa si ori mi, emi si mu aiya opo kọrin fun ayọ̀.
14Emi si mu ododo wọ̀, o si bò mi lara; idajọ mi dabi aṣọ igunwa ati ade ọba.
15Mo ṣe oju fun afọju, ati ẹsẹ̀ fun amọkún.
16Mo ṣe baba fun talaka, ati ọ̀ran ti emi kò mọ̀, mo wadi rẹ̀ ri.
17Mo si ká ehin ẹ̀rẹkẹ enia buburu, mo si ja ohun ọdẹ na kuro li ehin rẹ̀.
18Nigbana ni mo wipe, emi o kú ninu itẹ mi, emi o si mu ọjọ mi pọ̀ si i bi iyanrin (bi ọjọ ti ẹiyẹ Feniksi).
19Gbongbo mi ta lọ si ibi omi, ìri si sẹ̀ si ara ẹká mi titi li oru.
20Ogo mi gberu lọdọ mi, ọrun mi si pada di titun li ọwọ mi.
21Emi li enia ndẹti silẹ si, nwọn a si duro, nwọn a si dakẹ ninu ìgbimọ mi.
22Lẹhin ọ̀rọ mi nwọn kò si tun sọ mọ́, ọ̀rọ mi bọ́ si wọn li eti.
23Nwọn a si duro dè mi bi ẹnipe fun ojo; nwọn si yanu wọn gboro bi ẹnipe fun ojo àrọ-kuro.
24Emi si rẹrin si wọn nigbati nwọn kò ba gba a gbọ́; imọlẹ oju mi ni nwọn kò le imu rẹ̀wẹsi.
25Mo la ọ̀na silẹ fun wọn, mo si joko bi Olu, mo si joko bi ọba ninu ogun, bi ẹniti ntù aṣọ̀fọ̀ ninu.

Currently Selected:

Job 29: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy