YouVersion Logo
Search Icon

Esek 34

34
1Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2Ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn oluṣọ́ agutan Israeli, sọtẹlẹ, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn oluṣọ́ agutan; pe, Egbé ni fun awọn oluṣọ́ agutan Israeli, ti mbọ́ ara wọn, awọn oluṣọ́ agutan kì ba bọ́ ọwọ́-ẹran?
3Ẹnyin jẹ ọrá, ẹ si fi irun agutan bora, ẹ pa awọn ti o sanra: ẹ kò bọ́ agbo-ẹran.
4Ẹnyin kò mu alailera lara le, bẹ̃ni ẹ kò mu eyiti kò sàn li ara da, bẹ̃ni ẹ kò dì eyiti a ṣá lọ́gbẹ, bẹ̃ni ẹ kò tun mu eyi ti a ti lé lọ padà bọ̀, bẹ̃ni ẹ kò wá eyiti o sọnu, ṣugbọn ipá ati ìka li ẹ ti fi nṣe akoso wọn.
5A si tú wọn ka, nitori ti oluṣọ́ agutan kò si: nwọn si di onjẹ fun gbogbo ẹranko igbẹ́, nigbati a tú wọn ka.
6Awọn agutàn mi ṣako ni gbogbo òke, ati lori gbogbo òke kékèké, nitõtọ, a tú ọwọ́-ẹran mi ká ilẹ gbogbo, ẹnikẹni kò bere wọn ki o si wá wọn lọ.
7Nitorina ẹnyin oluṣọ́ agutan, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa.
8Bi mo ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, nitõtọ, nitori ti ọwọ́-ẹran mi di ijẹ, ti ọwọ́-ẹran mi di onjẹ fun olukuluku ẹranko igbẹ́, nitoriti kò si oluṣọ́ agutan, bẹ̃ni awọn oluṣọ́ agutan kò wá ọwọ́-ẹran mi ri, ṣugbọn awọn oluṣọ́ agutan bọ́ ara wọn, nwọn kò si bọ́ ọwọ́-ẹran mi.
9Nitorina, ẹnyin oluṣọ́ agutan, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa;
10Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi dojukọ awọn oluṣọ́ agutan; emi o si bere ọwọ́-ẹ̀ran mi lọwọ wọn, emi o si mu wọn dẹ́kun ati ma bọ́ awọn ọwọ́-ẹran: bẹ̃ni awọn ọluṣọ́ agutan kì yio bọ́ ara wọn mọ, nitori ti emi o gbà ọwọ́-ẹran mi kuro li ẹnu wọn ki nwọn ki o má ba jẹ onjẹ fun wọn.
11Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi, ani emi, o bere awọn agutan mi, emi o si wá wọn ri.
12Gẹgẹ bi oluṣọ́ agutan iti iwá ọwọ́-ẹran rẹ̀ ri, li ọjọ ti o wà lãrin awọn agutan rẹ̀ ti o fọnka, bẹ̃li emi o wá agutan mi ri, emi o si gbà wọn nibi gbogbo ti wọn ti fọnka si, li ọjọ kũkũ ati okùnkun biribiri.
13Emi o si mu wọn jade kuro ninu awọn orilẹ-ède, emi o si kó wọn jọ lati ilẹ gbogbo, emi o si mu wọn wá si ilẹ ara wọn, emi o si bọ́ wọn lori oke Israeli, lẹba odò, ati ni ibi gbigbé ni ilẹ na.
14Emi o bọ́ wọn ni pápa oko daradara ati lori okè giga Israeli ni agbo wọn o wà: nibẹ ni nwọn o dubulẹ ni agbo daradara, pápa oko ọlọ́ra ni nwọn o si ma jẹ lori oke Israeli.
15Emi o bọ́ ọwọ́-ẹran mi, emi o si mu ki nwọn dubulẹ, li Oluwa Ọlọrun wi.
16Emi o wá eyiti o sọnu lọ, emi o si mu eyiti a lé lọ pada bọ̀, emi o si dì eyiti a ṣá lọ́gbẹ, emi o mu eyiti o ṣaisan li ara le; ṣugbọn emi o run eyiti o sanra ati eyiti o lagbara; emi o fi idajọ bọ́ wọn.
17Bi o ṣe ti nyin, Ẹnyin ọwọ́-ẹran mi, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i emi o ṣe idajọ lãrin ẹran ati ẹran, lãrin àgbo ati obukọ.
18Ohun kekere ni li oju nyin ti ẹ ti jẹ oko daradara, ṣugbọn ẹnyin si fi ẹsẹ tẹ̀ oko iyokù mọlẹ, ati ti ẹ ti mu ninu omi jijìn, ṣugbọn ẹ si fi ẹsẹ ba eyi ti o kù jẹ?
19Bi o ṣe ti ọwọ́-ẹran mi ni, nwọn jẹ eyiti ẹ ti fi ẹsẹ nyin tẹ̀ mọlẹ; nwọn si mu eyiti ẹ ti fi ẹsẹ nyin bajẹ.
20Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun wọn, Kiyesi, emi, ani emi, o ṣe idajọ lãrin ọwọ́-ẹran ti o sanra, ati eyiti o rù.
21Nitoriti ẹnyin ti fi ẹgbẹ́ ati ejiká gbún, ti ẹ si ti fi iwo nyin kàn gbogbo awọn ti o li àrun titi ẹ fi tú wọn kakiri.
22Nitorina ni emi o ṣe gbà ọwọ́-ẹran mi là, nwọn kì yio si jẹ ijẹ́ mọ, emi o si ṣe idajọ lãrin ẹran ati ẹran.
23Emi o si gbe oluṣọ́ agutan kan soke lori wọn, on o si bọ́ wọn, ani Dafidi iranṣẹ mi; on o bọ́ wọn, on o si jẹ oluṣọ́ agutan wọn.
24Emi Oluwa yio si jẹ Ọlọrun wọn, ati Dafidi iranṣẹ mi o jẹ ọmọ-alade li ãrin wọn, emi Oluwa li o ti sọ ọ.
25Emi o si ba wọn da majẹmu alafia, emi o si jẹ ki awọn ẹranko buburu dasẹ ni ilẹ na: nwọn o si ma gbe aginju li ailewu, nwọn o si sùn ninu igbó.
26Emi o si ṣe awọn ati ibi ti o yi oke mi ká ni ibukún; emi o si jẹ ki ojò ki o rọ̀ li akoko rẹ̀, òjo ibukún yio wà.
27Igi igbẹ́ yio si so eso rẹ̀, ilẹ yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá, nwọn o si wà li alafia ni ilẹ wọn, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o ti ṣẹ́ èdídi àjaga wọn, ti emi o si ti gbà wọn lọwọ awọn ti nwọn nsìn bi ẹrú.
28Nwọn kì yio si ṣe ijẹ fun awọn keferi mọ, bẹ̃ni ẹranko ilẹ na kì yio pa wọn jẹ, ṣugbọn nwọn o wà li alafia ẹnikẹni kì yio si dẹrùba wọn,
29Emi o si gbe igi okiki kan soke fun wọn, ebi kì yio si run wọn ni ilẹ na mọ, bẹ̃ni nwọn kì yio rù itiju awọn keferi mọ.
30Bayi ni nwọn o mọ̀ pe emi Oluwa Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn, ati awọn, ile Israeli, jẹ enia mi, li Oluwa Ọlọrun wi.
31Ati ẹnyin ọwọ́-ẹran mi, ọwọ́-ẹran pápa oko mi ni enia, emi si li Ọlọrun nyin, li Oluwa Ọlọrun wi.

Currently Selected:

Esek 34: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in