YouVersion Logo
Search Icon

Esek 35

35
1Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2Ọmọ enia, kọ oju rẹ si oke Seiri, ki o si sọtẹlẹ si i.
3Ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Kiyesi i, iwọ oke Seiri, emi dojukọ ọ, emi o nà ọwọ́ mi si ọ, emi o si sọ ọ di ahoro patapata.
4Emi o sọ awọn ilu rẹ di ahoro, iwọ o si di ahoro, iwọ o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
5Nitori ti iwọ ti ni irira lailai, iwọ si ti fi awọn ọmọ Israeli le idà lọwọ́, li akoko idãmu wọn, li akoko ti aiṣedẽde wọn de opin.
6Nitorina, bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, emi o pèse rẹ silẹ fun ẹ̀jẹ, ẹ̀jẹ yio si lepa rẹ: bi iwọ kò ti korira ẹ̀jẹ nì, ẹ̀jẹ yio lepa rẹ.
7Bayi li emi o sọ oke Seiri di ahoro patapata, emi o si ké ẹniti nkọja lọ ati ẹniti npadà bọ̀ kuro ninu rẹ̀.
8Emi o si fi awọn okú rẹ̀ kún awọn oke rẹ̀; ni oke kékèké rẹ, ati ni afonifoji rẹ, ati ni gbogbo odò rẹ li awọn ti a fi idà pa yio ṣubu si.
9Emi o sọ ọ di ahoro lailai, awọn ilu rẹ kì yio si padà bọ̀: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
10Nitoriti iwọ ti wipe, Awọn orilẹ-ède mejeji yi, ati awọn ilẹ mejeji yi yio jẹ́ ti emi, awa o si ni i; nigbati o ṣepe Oluwa wà nibẹ:
11Nitorina, bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi emi o tilẹ ṣe gẹgẹ bi ibinu rẹ, ati gẹgẹ bi ilara rẹ ti iwọ ti lò lati inu irira rẹ si wọn; emi o si sọ ara mi di mimọ̀ lãrin wọn, nigbati emi ba ti da ọ li ẹjọ.
12Iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa, ati pe emi ti gbọ́ ọ̀rọ buburu rẹ, ti iwọ ti sọ si oke Israeli, wipe, A sọ wọn di ahoro, a fi wọn fun wa lati run.
13Bayi li ẹnyin ti fi ẹnu nyin buná si mi, ẹ si ti sọ ọ̀rọ nyin di pupọ si mi: emi ti gbọ́.
14Bayi li Oluwa Ọlọrun wi pe, Nigbati gbogbo aiye nyọ̀, emi o sọ ọ di ahoro.
15Gẹgẹ bi iwọ ti yọ̀ si ini ile Israeli, nitori ti o di ahoro, bẹ̃li emi o ṣe si ọ; iwọ o di ahoro, iwọ oke Seiri ati gbogbo Idumea, ani gbogbo rẹ̀: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Currently Selected:

Esek 35: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in