1
Esek 34:16
Bibeli Mimọ
Emi o wá eyiti o sọnu lọ, emi o si mu eyiti a lé lọ pada bọ̀, emi o si dì eyiti a ṣá lọ́gbẹ, emi o mu eyiti o ṣaisan li ara le; ṣugbọn emi o run eyiti o sanra ati eyiti o lagbara; emi o fi idajọ bọ́ wọn.
Compare
Explore Esek 34:16
2
Esek 34:12
Gẹgẹ bi oluṣọ́ agutan iti iwá ọwọ́-ẹran rẹ̀ ri, li ọjọ ti o wà lãrin awọn agutan rẹ̀ ti o fọnka, bẹ̃li emi o wá agutan mi ri, emi o si gbà wọn nibi gbogbo ti wọn ti fọnka si, li ọjọ kũkũ ati okùnkun biribiri.
Explore Esek 34:12
3
Esek 34:11
Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi, ani emi, o bere awọn agutan mi, emi o si wá wọn ri.
Explore Esek 34:11
4
Esek 34:15
Emi o bọ́ ọwọ́-ẹran mi, emi o si mu ki nwọn dubulẹ, li Oluwa Ọlọrun wi.
Explore Esek 34:15
5
Esek 34:31
Ati ẹnyin ọwọ́-ẹran mi, ọwọ́-ẹran pápa oko mi ni enia, emi si li Ọlọrun nyin, li Oluwa Ọlọrun wi.
Explore Esek 34:31
6
Esek 34:2
Ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn oluṣọ́ agutan Israeli, sọtẹlẹ, ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn oluṣọ́ agutan; pe, Egbé ni fun awọn oluṣọ́ agutan Israeli, ti mbọ́ ara wọn, awọn oluṣọ́ agutan kì ba bọ́ ọwọ́-ẹran?
Explore Esek 34:2
Home
Bible
Plans
Videos