I. Kro 17
17
Iṣẹ́ tí Natani Jẹ́ fún Dafidi
(II. Sam 7:1-17)
1O SI ṣe, bi Dafidi ti joko ninu ile rẹ̀, ni Dafidi sọ fun Natani woli pe, Wò o, emi ngbe inu ile kedari, ṣugbọn apoti ẹri majẹmu Oluwa ngbe abẹ aṣọ-tita.
2Nigbana ni Natani wi fun Dafidi pe, Ṣe ohun gbogbo ti mbẹ ni inu rẹ; nitoriti Ọlọrun wà pẹlu rẹ.
3O si ṣe li oru kanna ni ọ̀rọ Ọlọrun tọ Natani wá, wipe,
4Lọ, si sọ fun Dafidi iranṣẹ mi pe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun mi lati ma gbe.
5Nitori emi kò ti igbe inu ile lati ọjọ ti mo ti mu Israeli gòke wá titi fi di oni yi; ṣugbọn emi nlọ lati agọ de agọ, ati lati ibugbe kan de keji.
6Nibikibi ti mo ti nrin larin gbogbo Israeli, emi ha sọ̀rọ kan fun ọkan ninu awọn onidajọ Israeli, ti emi ti paṣẹ fun lati ma bọ awọn enia mi, emi ha ti wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi kọ́ ile igi kedari fun mi bi?
7Njẹ nitorina bayi ni iwọ o wi fun Dafidi iranṣẹ mi, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Emi mu ọ kuro ni pápá oko-tutu, ani kuro lati ma tọ agutan lẹhin, ki iwọ ki o le ma ṣe olori awọn enia mi Israeli.
8Emi si ti wà pẹlu rẹ ni ibikibi ti iwọ ba lọ, emi si ti ké gbogbo awọn ọta rẹ kuro niwaju rẹ, emi o si ṣe ọ li olorukọ kan, bi orukọ awọn enia nla ti o ti wà li aiye.
9Emi o si yan ibi kan fun Israeli awọn enia mi, emi o si gbìn wọn, ki nwọn le má gbe ipò wọn, a kì yio si ṣì wọn mọ; bẹ̃ni ọmọ buburu kì yio yọ wọn lẹnu mọ, bi ti atijọ;
10Ati bi igba ti emi ti fi enia jẹ onidajọ lori awọn enia mi Israeli. Ati pẹlu emi o ṣẹgun gbogbo awọn ọta rẹ. Pẹlupẹlu mo ti sọ fun ọ pe, Oluwa yio kọle kan fun ọ.
11Yio si ṣe, nigbati ọjọ rẹ ba pe, ti iwọ o lọ pẹlu awọn baba rẹ, ni emi o gbé iru-ọmọ rẹ dide lẹhin rẹ, ti yio jẹ ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin; emi o si fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ.
12On o kọ́ ile fun mi, emi o si fi idi itẹ rẹ̀ mulẹ lailai.
13Emi o jẹ baba fun u, on o si jẹ ọmọ fun mi; emi kì yio si gbà ãnu mi kuro lọdọ rẹ̀, bi mo ti gbà a lọwọ ẹniti o ti wà ṣaju rẹ:
14Ṣugbọn emi o fi idi rẹ̀ kalẹ ninu ile mi ati ninu ijọba mi lailai, a o si fi idi itẹ rẹ̀ mulẹ lailai.
15Gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi, ati gẹgẹ bi gbogbo iran yi, bẹ̃ni Natani sọ fun Dafidi.
Adura Ọpẹ́ tí Dafidi Gbà
(II. Sam 7:18-29)
16Dafidi ọba si wá, o si joko niwaju Oluwa, o si wipe, Tali emi Oluwa Ọlọrun, ati kini ile mi, ti iwọ si mu mi de ihinyi?
17Ohun kekere si li eyi li oju rẹ, Ọlọrun: iwọ si ti sọ pẹlu sipa ile iranṣẹ rẹ fun akokò jijin ti mbọ, o si ka mi si bi iṣe enia giga, Oluwa Ọlọrun.
18Kini Dafidi le tun ma sọ pẹlu fun ọ niti ọlá ti a bù fun iranṣẹ rẹ? iwọ sa mọ̀ iranṣẹ rẹ.
19Oluwa, nitoriti iranṣẹ rẹ, ati gẹgẹ bi ti inu rẹ, ni iwọ ti ṣe gbogbo ohun nlanla yi, ni sisọ gbogbo nkan nla wọnyi di mimọ̀.
20Oluwa, kò si ẹniti o dabi rẹ bẹ̃ni kò si Ọlọrun miran lẹhin rẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti awa ti fi eti wa gbọ́.
21Orilẹ-ède kan wo li o wà li aiye ti o dabi enia rẹ, Israeli, ti Ọlọrun lọ irapada lati ṣe enia on tikararẹ, lati ṣe orukọ fun ara rẹ nipa ohun ti o tobi ti o si lẹ̀ru, ni lile awọn orilẹ-ède jade kuro niwaju awọn enia rẹ, ti iwọ ti rapada lati Egipti jade wá?
22Nitori awọn enia rẹ Israeli li o ti ṣe li enia rẹ titi lai; iwọ Oluwa, si di Ọlọrun wọn.
23Njẹ nisisiyi, Oluwa! jẹ ki ọ̀rọ ti iwọ ti sọ niti iranṣẹ rẹ, ati niti ile rẹ̀ ki o fi idi mulẹ lailai, ki iwọ ki o si ṣe bi iwọ ti wi.
24Ani, jẹ ki o fi idi mulẹ, ki a le ma gbé orukọ rẹ ga lailai, wipe, Oluwa awọn ọmọ ogun li Ọlọrun Israeli, ani Ọlọrun fun Israeli; si jẹ ki ile Dafidi iranṣẹ rẹ ki o fi idi mulẹ niwaju rẹ.
25Nitori iwọ, Ọlọrun mi, ti ṣi iranṣẹ rẹ li eti pe, Iwọ o kọ́ ile kan fun u: nitorina ni iranṣẹ rẹ ri i lati gbadua niwaju rẹ.
26Njẹ nisisiyi Oluwa, Iwọ li Ọlọrun, iwọ si ti sọ ọ̀rọ ore yi fun iranṣẹ rẹ;
27Njẹ nisisiyi jẹ ki o wù ọ lati bukún ile iranṣẹ rẹ, ki o le ma wà niwaju rẹ lailai: nitori iwọ Oluwa, ẹniti o sure fun, ire ni o si ma jẹ lailai.
Currently Selected:
I. Kro 17: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.