YouVersion Logo
Search Icon

I. Kro 16

16
1BẸ̀NI nwọn mu apoti ẹri Ọlọrun wá, nwọn si fi si arin agọ na ti Dafidi pa fun u: nwọn si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia niwaju Ọlọrun,
2Nigbati Dafidi si ti pari riru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia tan, o sure fun awọn enia li orukọ Oluwa.
3O si fi fun gbogbo enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin fun olukulùku iṣu akara kan, ati ekiri ẹran kan, ati akara didùn kan.
4O si yan ninu awọn ọmọ Lefi lati ma jọsin niwaju apoti ẹri Oluwa, ati lati ṣe iranti, ati lati dupẹ, ati lati yìn Oluwa Ọlọrun Israeli:
5Asafu ni olori, ati atẹle rẹ̀ ni Sekariah, Jeieli, ati Ṣemiramotu, ati Jehieli, ati Mattitiah, ati Eliabu, ati Benaiah, ati Obed-Edomu: ati Jeieli pẹlu psalteri ati pẹlu duru; ṣugbọn Asafu li o nlù kimbali kikan;
6Benaiah pẹlu ati Jahasieli awọn alufa pẹlu ipè nigbagbogbo niwaju apoti ẹri ti majẹmu Ọlọrun.
7Li ọjọ na ni Dafidi kọ́ fi orin mimọ́ yi le Asafu lọwọ lati dupẹ lọwọ Oluwa.
Orin Ìyìn
(O. Daf 105:1-15; 96:1-13; 106:1,47-48)
8Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, ẹ pè orukọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia.
9Ẹ kọrin si i, ẹ kọ́ orin mimọ́ si i, ẹ ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ̀.
10Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki ọkàn awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀.
11Ẹ ma wá Oluwa, ati ipa rẹ̀, ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo.
12Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe, iṣẹ àmi rẹ̀, ati idajọ ẹnu rẹ̀;
13Ẹnyin iru-ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ̀, ẹnyin ọmọ Jakobu ayanfẹ rẹ̀.
14On ni Oluwa Ọlọrun wa, idajọ rẹ̀ mbẹ ni gbogbo aiye.
15Ẹ ma ṣe iranti majẹmu rẹ̀ titi lai, ọ̀rọ ti o ti pa li aṣẹ fun ẹgbẹrun iran;
16Majẹmu ti o ba Abrahamu da, ati ibura rẹ̀ fun Isaaki;
17A si tẹnumọ eyi li ofin fun Jakobu, ati fun Israeli ni majẹmu aiyeraiye:
18Wipe, Iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin.
19Nigbati ẹnyin wà ni kiun ni iye, ani diẹ kiun, ati atipo ninu rẹ̀.
20Nwọn si nlọ lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, ati lati ijọba kan de ọdọ enia miran;
21On kò jẹ ki ẹnikẹni ki o ṣe wọn ni ìwọsi, nitõtọ, o ba awọn ọba wi nitori wọn,
22Wipe, Ẹ má ṣe fi ọwọ kan ẹni-ororo mi, ẹ má si ṣe awọn woli mi ni ibi.
23Ẹ kọrin titun si Oluwa gbogbo aiye; ẹ ma fi igbala rẹ̀ hàn lati ọjọ de ọjọ.
24Ẹ sọ̀rọ ogo rẹ̀ ninu awọn keferi; ati iṣẹ-iyanu rẹ̀ ninu gbogbo enia.
25Nitori titobi li Oluwa, o si ni iyìn gidigidi: on li o si ni ibẹ̀ru jù gbogbo oriṣa lọ.
26Nitori pe gbogbo oriṣa awọn enia, ere ni nwọ́n: ṣugbọn Oluwa li o da awọn ọrun.
27Ogo on ọlá wà niwaju rẹ̀; agbara ati ayọ̀ mbẹ ni ipò rẹ̀.
28Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipa fun Oluwa.
29Ẹ fi ogo fun Oluwa ti o yẹ fun orukọ rẹ̀: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá siwaju rẹ̀: ẹ sin Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́.
30Ẹ warìri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye, aiye pẹlu si fi idi mulẹ ti kì o fi le yi.
31Jẹ ki awọn ọrun ki o yọ̀, si jẹ ki inu aiye ki o dùn; si jẹ ki a wi ninu awọn orilẹ-ède pe, Oluwa jọba.
32Jẹ ki okun ki o ma ho, ati ẹkún rẹ̀: jẹ ki papa-oko tùtu ki o yọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀.
33Nigbana ni awọn igi igbo yio ma ho niwaju Oluwa, nitori ti o mbọ wá ṣe idajọ aiye.
34Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.
35Ki ẹ si wipe, Gbà wa Ọlọrun igbala wa, si gbá wa jọ, ki o si gbà wa lọwọ awọn keferi, ki awa ki o le ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ mimọ́, ki a si le ma ṣogo ninu iyin rẹ.
36Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli lai ati lailai. Gbogbo awọn enia si wipe, Amin, nwọn si yìn Oluwa.
Ìjọ́sìn ní Gibeoni ati ní Jerusalẹmu
37Bẹ̃ li o fi Asafu ati awọn arakunrin rẹ̀ silẹ nibẹ niwaju apoti ẹri majẹmu Oluwa lati ma jọsìn niwaju apoti ẹri na nigbagbogbo, bi iṣẹ ojojumọ ti nfẹ.
38Ati Obed-Edomu pẹlu awọn arakunrin wọn, enia mejidilãdọrin; ati Obed-Edomu ọmọ Jedutuni, ati Hosa lati ma ṣe adena:
39Sadoku alufa, ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn alufa, niwaju agọ Oluwa, ni ibi giga ti o wà ni Gibeoni,
40Lati ma ru ẹbọ sisun si Oluwa lori pẹpẹ ẹbọ sisun nigbagbogbo li owurọ ati li alẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti a kọ ninu ofin Oluwa, ti o pa li aṣẹ fun Israeli;
41Ati pẹlu wọn Hemani ati Jedutuni, ati awọn iyokù ti a yàn, ti a si pe li orukọ, lati ma fi ìyin fun Oluwa, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai;
42Ati pẹlu wọn Hemani ati Jedutuni pẹlu ipè ati kimbali fun awọn ti yio ma pariwo, ati pẹlu ohun èlo orin Ọlọrun. Awọn ọmọ Jedutuni li awọn adena.
43Gbogbo awọn enia si lọ olukuluku si ile rẹ̀: Dafidi yipada lati sure fun ile rẹ̀.

Currently Selected:

I. Kro 16: YBCV

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in