I. Kro 18
18
Àwọn Ogun tí Dafidi Jà ní Àjàṣẹ́gun
(II. Sam 8:1-18)
1O SI ṣe lẹhin eyi, ni Dafidi kọlu awọn ara Filistia, o si ṣẹ́ wọn, o si gbà Gati ati ilu rẹ̀ lọwọ awọn ara Filistia.
2O si kọlu Moabu, awọn ara Moabu si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá.
3Dafidi si kọlu Hadareseri ọba Soba ni Hamati bi o ti nlọ lati fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ leti odò Euferate.
4Dafidi si gbà ẹgbẹrun kẹkẹ́, ati ẹ̃dẹgbarun ẹlẹṣin, ati ẹgbãwa ẹlẹsẹ lọwọ rẹ̀: Dafidi si ja iṣan ẹsẹ gbogbo awọn ẹṣin kẹkẹ́ na, ṣugbọn o pa ọgọrun ẹṣin kẹkẹ́ mọ ninu wọn.
5Nigbati awọn ara Siria ti Damasku wá lati ran Hadareseri ọba Soba lọwọ, Dafidi pa ẹgbã mọkanla enia ninu awọn ara Siria.
6Dafidi si fi ẹgbẹ-ogun si Siria ti Damasku; awọn ara Siria si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá. Bayi li Oluwa gbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ.
7Dafidi si gbà awọn asa wura ti mbẹ lara awọn iranṣẹ Hadareseri, o si mu wọn wá si Jerusalemu.
8Lati Tibhati pẹlu ati lati Kuni, ilu Hadareseri ni Dafidi ko ọ̀pọlọpọ idẹ, eyiti Solomoni fi ṣe okun idẹ, ọwọn wọnni, ati ohun elo idẹ wọnni.
9Nigbati Tou ọba Hamati gbọ́ pe Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadareseri ọba Soba.
10O ran Hadoramu ọmọ rẹ̀ si Dafidi ọba lati ki i ati lati yọ̀ fun u, nitoriti o ti ba Hadareseri jà o si ti ṣẹgun rẹ̀; (nitori Tou ti jẹ ọta Hadareseri) o si ni oniruru ohun elo wura ati ti fadakà ati idẹ pẹ̀lu rẹ̀.
11Awọn pẹlu ni Dafidi yà si mimọ́ fun Oluwa pẹlu fadakà ati wura ti o ko lati ọdọ gbogbo orilẹ-ède wọnni wá; lati Edomu, ati lati Moabu, ati lati ọdọ awọn ọmọ Ammoni, ati lati ọdọ awọn ara Filistia, ati lati Amaleki wá,
12Pẹlupẹlu Abiṣai ọmọ Seruiah pa ẹgbãsan ninu awọn ara Edomu li afonifoji Iyọ̀.
13O si fi ẹgbẹ-ogun si Edomu: ati gbogbo awọn ara Edomu si di iranṣẹ Dafidi. Bayi li Oluwa ngbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ.
14Bẹ̃ ni Dafidi jọba lori gbogbo Israeli, o si ṣe idajọ ati otitọ larin awọn enia rẹ̀.
15Joabu ọmọ Seruiah si wà lori ogun; ati Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni akọwe-iranti.
16Sadoku ọmọ Ahitubu, ati Abimeleki ọmọ Abiatari, li awọn alufa; ati Ṣafṣa ni akọwe;
17Benaiah ọmọ Jehoiada li o si wà lori awọn Kereti ati awọn Peleti; awọn ọmọ Dafidi si li olori lọdọ ọba.
Currently Selected:
I. Kro 18: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.