I. Kro 19
19
Dafidi Ṣẹgun Àwọn Ará Amoni ati Àwọn Ará Siria
(II. Sam 10:1-19)
1O SI ṣe lẹhin eyi, ni Nahaṣi ọba awọn ọmọ Ammoni kú, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
2Dafidi si wipe, Emi o ṣe ore fun Hanuni ọmọ Nahaṣi, nitoriti baba rẹ̀ ṣe ore fun mi. Dafidi si ran onṣẹ lati tù u ninu nitori baba rẹ̀. Bẹ̃ni awọn iranṣẹ Dafidi wá si ilẹ awọn ọmọ Ammoni, si ọdọ Hanuni lati tù u ninu.
3Ṣugbọn awọn ijoye awọn ọmọ Ammoni wi fun Hanuni pe, Iwọ rò pe Dafidi bu ọlá fun baba rẹ nitori ti o ran awọn olutunu si ọ? Kò ṣepe awọn iranṣẹ rẹ̀ wá si ọdọ rẹ lati rin wò, ati lati bi ṣubu ati lati ṣe ami ilẹ na?
4Nitorina Hanuni kó awọn iranṣẹ Dafidi, o si fa irungbọn wọn, o si ké agbáda wọn sunmọ ibadi wọn, o ran wọn lọ.
5Nigbana ni awọn kan lọ, nwọn si sọ fun Dafidi bi a ti ṣe awọn ọkunrin na: on si ranṣẹ lọ ipade wọn: nitori oju tì awọn ọkunrin na gidigidi. Ọba si wipe, Ẹ duro ni Jeriko titi irungbọn nyin yio fi hù, nigbana ni ki ẹ si pada wá.
6Nigbati awọn ọmọ Ammoni ri pe nwọn ti ba ara wọn jẹ lọdọ Dafidi, Hanuni ati awọn ọmọ Ammoni ran ẹgbẹrun talenti fadakà lati bẹ̀wẹ kẹkẹ́ ati ẹlẹsin lati Siria ni Mesopotamia wá, ati lati Siria-Maaka wá, ati lati Soba wá.
7Bẹ̃ni nwọn bẹwẹ ẹgbã mẹrindilogun kẹkẹ́ ati ọba Maaka ati awọn enia rẹ̀; nwọn si wá nwọn si do niwaju Medeba. Awọn ọmọ Ammoni si ko ara wọn jọ lati ilu wọn, nwọn si wá si ogun.
8Nigbati Dafidi gbọ́, o ran Joabu ati gbogbo ogun awọn akọni enia.
9Awọn ọmọ Ammoni si jade wá, nwọn si tẹ ogun niwaju ẹnu-ibode ilu na: awọn ọba ti o wá si wà li ọtọ̀ ni igbẹ.
10Nigbati Joabu ri pe a doju ija kọ on, niwaju ati lẹhin, o yàn ninu gbogbo ãyo Israeli, o si tẹ ogun wọn si awọn ara Siria.
11O si fi iyokù awọn enia le Abiṣai arakunrin rẹ̀ lọwọ, nwọn si tẹ ogun si awọn ọmọ Ammoni.
12On si wipe, Bi awọn ara Siria ba le jù fun mi, nigbana ni iwọ o ran mi lọwọ: ṣugbọn bi awọn ọmọ Ammoni ba le jù fun ọ, nigbana li emi o ràn ọ lọwọ.
13Ṣe giri ki o si jẹ ki a huwa akọni fun enia wa ati fun ilu Ọlọrun wa: ki Oluwa ki o si ṣe eyi ti o dara loju rẹ̀.
14Bẹ̃ni Joabu ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀ sún siwaju awọn ara Siria si ibi ija: nwọn si sá niwaju rẹ̀.
15Nigbati awọn ọmọ Ammoni si ri pe awọn ara Siria sá, awọn pẹlu sá niwaju Abiṣai arakunrin rẹ̀, nwọn si wọ̀ ilu lọ. Nigbana ni Joabu wá si Jerusalemu.
16Nigbati awọn ara Siria ri pe a le wọn niwaju Israeli, nwọn ran onṣẹ, nwọn si fà awọn ara Siria ti mbẹ lòke odò: Ṣofaki olori ogun Hadareseri sì ṣiwaju wọn.
17A si sọ fun Dafidi; on si ko gbogbo Israeli jọ, o si gòke odò Jordani o si yọ si wọn, o si tẹ ogun si wọn. Bẹ̃ni nigbati Dafidi tẹ ogun si awọn ara Siria, nwọn ba a jà.
18Ṣugbọn awọn ara Siria sá niwaju Israeli, Dafidi si pa ẹ̃dẹgbarin enia ninu awọn ara Siria ti o wà ninu kẹkẹ́, ati ọkẹ-meji ẹlẹsẹ, o si pa Ṣofaki olori ogun na.
19Nigbati awọn iranṣẹ Hadareseri ri pe a le wọn niwaju Israeli, nwọn ba Dafidi làja, nwọn si nsìn i: bẹ̃ni awọn ara Siria kò jẹ ràn awọn ọmọ Ammoni lọwọ mọ.
Currently Selected:
I. Kro 19: YBCV
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.