ORIN DAFIDI 31
31
Adura Igbẹkẹle Ọlọrun
1OLUWA, ìwọ ni mo sá di,
má jẹ́ kí ojú tì mí lae;
gbà mí, nítorí olóòótọ́ ni ọ́.
2Dẹ etí sí mi, yára gbà mí.
Jẹ́ àpáta ààbò fún mi;
àní ilé ààbò tó lágbára láti gbà mí là.
3Ìwọ ni àpáta ati ilé ààbò mi;
nítorí orúkọ rẹ, máa tọ́ mi kí o sì máa fọ̀nà hàn mí.
4Yọ mí kúrò ninu àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ dè mí,
nítorí ìwọ ni ẹni ìsádi mi.
5Ìwọ ni mo fi ẹ̀mí mi lé lọ́wọ́,
o ti rà mí pada, OLUWA, Ọlọrun, olóòótọ́.#Luk 23:46
6Mo kórìíra àwọn tí ń bọ oriṣa lásánlàsàn,
ṣugbọn OLUWA ni èmi gbẹ́kẹ̀lé.
7N óo máa yọ̀, inú mi óo sì máa dùn,
nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;
nítorí pé o ti rí ìpọ́njú mi,
o sì mọ ìṣòro mi.
8O ò fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́,
o sì ti fi ẹsẹ̀ mi lé ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
9Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí pé mo wà ninu ìṣòro.
Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì;
àárẹ̀ sì mú ọkàn ati ara mi.
10Nítorí pé ìbànújẹ́ ni mo fi ń lo ayé mi;
ìmí ẹ̀dùn ni mo sì fi ń lo ọdún kan dé ekeji.
Ìpọ́njú ti gba agbára mi;
gbogbo egungun mi sì ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ.
11Ẹni ẹ̀gàn ni mí láàrin gbogbo àwọn ọ̀tá mi,
àwòsọkún ni mí fún àwọn aládùúgbò.
Mo di àkòtagìrì fún àwọn ojúlùmọ̀ mi,
àwọn tí ó rí mi lóde sì ń sá fún mi.
12Mo di ẹni ìgbàgbé bí ẹni tí ó ti kú;
mo dàbí àkúfọ́ ìkòkò.
13Mò ń gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,
bí wọ́n ti ń gbìmọ̀ pọ̀ nípa mi,
tí wọ́n sì ń pète ati pa mí;
wọ́n ń ṣẹ̀rù bà mí lọ́tùn-ún lósì.
14Ṣugbọn, mo gbẹ́kẹ̀lé ọ, OLUWA,
Mo ní, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.”
15Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi,
ati lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi.
16Jẹ́ kí èmi iranṣẹ rẹ rí ojurere rẹ,
gbà mí là, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
17Má jẹ́ kí ojú tì mí, OLUWA,
nítorí ìwọ ni mò ń ké pè.
Jẹ́ kí ojú ti àwọn eniyan burúkú;
jẹ́ kí ẹnu wọn wọ wòwò títí wọ ibojì.
18Jẹ́ kí àwọn òpùrọ́ yadi,
àní àwọn tí ń fi ìgbéraga ati ẹ̀gàn sọ̀rọ̀ àìdára nípa olódodo.
19Háà! Ohun rere mà pọ̀ lọ́wọ́ rẹ o
tí o ti sọ lọ́jọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
tí o sì ti pèsè ní ìṣojú àwọn ọmọ eniyan,
fún àwọn tí ó sá di ọ́.
20O fi ìyẹ́ apá rẹ ṣíji bò wọ́n;
o pa wọ́n mọ́ kúrò ninu rìkíṣí àwọn eniyan;
o sì pa wọ́n mọ́ lábẹ́ ààbò rẹ,
kúrò lọ́wọ́ ẹnu àwọn ẹlẹ́jọ́ wẹ́wẹ́.
21Ẹni ìyìn ni OLUWA, nítorí pé, lọ́nà ìyanu,
ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí,
nígbà tí ilẹ̀ ká mi mọ́.
22Ẹ̀rù bà mí, mo sì sọ pé,
“A lé mi jìnnà kúrò ní iwájú rẹ.”
Ṣugbọn o gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi
nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.
23Ẹ fẹ́ràn OLUWA, gbogbo ẹ̀yin olódodo,
OLUWA a máa ṣọ́ àwọn olóòótọ́,
a sì máa san àlékún ẹ̀san fún àwọn agbéraga.
24Ẹ múra gírí, kí ẹ sì mọ́kàn le,
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.
Currently Selected:
ORIN DAFIDI 31: YCE
Highlight
Share
Copy
Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in
Bible Society of Nigeria © 1900/2010