YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 30

30
Adura Ọpẹ́
1N óo yìn ọ́, OLUWA,
nítorí pé o ti yọ mí jáde;
o kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
2OLUWA, Ọlọrun mi, mo ké pè ọ́,
o sì wò mí sàn.
3OLUWA, o ti yọ mí kúrò ninu isà òkú
o sọ mí di ààyè láàrin àwọn tí
wọ́n ti wọ inú kòtò.
4Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWA, ẹ̀yin olùfọkànsìn rẹ̀,
kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.
5Nítorí pé fún ìgbà díẹ̀ ni ibinu rẹ̀,
ṣugbọn títí ayé ni ojurere rẹ̀;
eniyan lè máa sọkún títí di alẹ́,
ṣugbọn ayọ̀ ń bọ̀ fún un lówùúrọ̀.
6Nígbà tí ara rọ̀ mí,
mo wí ninu ọkàn mi pé,
kò sí ohun tí ó lè mì mí laelae.
7Nípa ojurere rẹ, OLUWA,
o ti fi ìdí mi múlẹ̀ bí òkè ńlá;
ṣugbọn nígbà tí o fi ojú pamọ́ fún mi,
ìdààmú dé bá mi.
8Ìwọ ni mò ń ké pè, OLUWA,
OLUWA, ìwọ ni mò ń bẹ̀.
9Anfaani wo ló wà ninu pé kí n kú?
Èrè wo ló wà ninu pé kí n wọ inú kòtò?
Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́?
Ṣé ó lè sọ nípa òdodo rẹ?
10Gbọ́ OLUWA, kí o sì ṣàánú mi,
OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.
11O ti bá mi sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó,
o ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò lára mi,
o sì ti dì mí ní àmùrè ayọ̀,
12kí ọkàn mi lè máa yìn ọ́ láìdákẹ́.
OLUWA Ọlọrun mi, n óo máa fi ọpẹ́ fún ọ títí lae.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 30: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in