YouVersion Logo
Search Icon

ORIN DAFIDI 32

32
Ìjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀
1Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí a dárí ìrékọjá rẹ̀ jì,
tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.
2Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí OLUWA kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn,
tí ẹ̀tàn kò sì sí ninu ọkàn rẹ̀.
3Nígbà tí n kò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi,
ó rẹ̀ mí wá láti inú,
nítorí kíkérora tí mò ń kérora ní gbogbo ìgbà.
4Nítorí tọ̀sán-tòru ni o fi ń jẹ mí níyà;
gbogbo agbára mi ló lọ háú,
bí omi tíí gbẹ lákòókò ẹ̀ẹ̀rùn.
5Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ;
n kò sì fi àìdára mi pamọ́ fún ọ.
Mo ní, “Èmi óo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Oluwa,”
o sì dáríjì mí.
6Nítorí náà, kí gbogbo olódodo máa gbadura sí ọ;
ní àkókò tí ìpọ́njú bá ń yí lura wọn bí ìṣàn omi ńlá,
kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn.
7Ìwọ ni ibi ìsásí mi;
o pa mí mọ́ kúrò ninu ìṣòro;
o sì fi ìgbàlà yí mi ká.
8N óo kọ́ ọ, n óo sì tọ́ ọ sí ọ̀nà tí o óo rìn;
n óo máa gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn;
n óo sì máa mójútó ọ.
9Má ṣe dàbí ẹṣin tabi ìbaaka,
tí kò ni ọgbọ́n ninu,
tí a gbọdọ̀ kó ìjánu sí lẹ́nu
kí ó tó lè gbọ́ ti oluwa rẹ̀.
10Ìrora pọ̀ fún àwọn eniyan burúkú,
ṣugbọn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ó yí àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ká.
11Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA;
ẹ fò fún ayọ̀, ẹ̀yin olódodo;
kí ẹ sì hó fún ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn mímọ́.

Currently Selected:

ORIN DAFIDI 32: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in