O. Daf 18:1-6
![O. Daf 18:1-6 - EMI o fẹ ọ, Oluwa, agbara mi.
Oluwa li apáta mi, ati ilu-olodi mi, ati olugbala mi: Ọlọrun mi, agbara mi, emi o gbẹkẹle e; asà mi, ati iwo igbala mi, ati ile-iṣọ giga mi.
Emi o kepè Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn; bẹ̃li a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi.
Irora ikú yi mi ka, ati iṣàn-omi awọn enia buburu dẹ̀ruba mi.
Irora ipò okú yi mi kakiri: ikẹkun ikú dì mi mu.
Ninu ìṣẹ́ mi emi kepè Oluwa, emi si sọkun pe Ọlọrun mi: o gbohùn mi lati inu tempili rẹ̀ wá, ẹkún mi si wá si iwaju rẹ̀, ani si eti rẹ̀.](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2F320x320%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fstatic-youversionapi-com%2Fimages%2Fbase%2F71219%2F1280x1280.jpg&w=640&q=75)
EMI o fẹ ọ, Oluwa, agbara mi. Oluwa li apáta mi, ati ilu-olodi mi, ati olugbala mi: Ọlọrun mi, agbara mi, emi o gbẹkẹle e; asà mi, ati iwo igbala mi, ati ile-iṣọ giga mi. Emi o kepè Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn; bẹ̃li a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi. Irora ikú yi mi ka, ati iṣàn-omi awọn enia buburu dẹ̀ruba mi. Irora ipò okú yi mi kakiri: ikẹkun ikú dì mi mu. Ninu ìṣẹ́ mi emi kepè Oluwa, emi si sọkun pe Ọlọrun mi: o gbohùn mi lati inu tempili rẹ̀ wá, ẹkún mi si wá si iwaju rẹ̀, ani si eti rẹ̀.
O. Daf 18:1-6