EMI o fẹ ọ, Oluwa, agbara mi. Oluwa li apáta mi, ati ilu-olodi mi, ati olugbala mi: Ọlọrun mi, agbara mi, emi o gbẹkẹle e; asà mi, ati iwo igbala mi, ati ile-iṣọ giga mi. Emi o kepè Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn; bẹ̃li a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi. Irora ikú yi mi ka, ati iṣàn-omi awọn enia buburu dẹ̀ruba mi. Irora ipò okú yi mi kakiri: ikẹkun ikú dì mi mu. Ninu ìṣẹ́ mi emi kepè Oluwa, emi si sọkun pe Ọlọrun mi: o gbohùn mi lati inu tempili rẹ̀ wá, ẹkún mi si wá si iwaju rẹ̀, ani si eti rẹ̀.
Kà O. Daf 18
Feti si O. Daf 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 18:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò