ỌGBỌ́NÀpẹrẹ

ỌGBỌ́N

Ọjọ́ 1 nínú 3

Ọgbọ́n: Ohun tó ṣe kókó

Ìrìnàjò ìgbàgbọ́ wa kò dúró ní gbígba Krístì, ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́, tàbí lílọ sí àwọn ètò ẹ̀sìn. Àwọn wọ̀nyí ṣe kókó láti dúró nínú ìgbàgbọ́ àti fún ìdàgbàsókè, ṣùgbọ́n a nílò láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn tí a ti mọ̀ kí á tó di onígbàgbọ́. A gbọ́dọ̀ ṣe àfihàn ìwà tòótọ́ ti ọmọ Ọlọ́run, ní ìbámu pẹ̀lú Krístì.

Nínú ìwé Ìṣe 11:19-26, Barnaba wá Sáàlù ó sì mú u wá sí Áńtíókù, níbi tí wọ́n tí kọ́ ìjọ fún ọdún kan. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn, fọ́nká látàrí inúnibíni, ni a kọ́kọ́ pè ní Krìstẹ́ní ní Áńtíókù. Orúkọ yìí ṣe àfihàn ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Krístì, ẹni tó mú ìdọ́gba bá ìfẹ́ àwọn ènìyàn àti èròǹgbà Baba nígbà tí ó wà ní àìṣẹ̀.

Òwe 4:7 sọ wípé, "Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n ni láti ní ọgbọ́n: àti pẹ̀lú ìní rẹ gbogbo, ní òye." Ní bí "gbòógì" túmọ̀ sí ohùn àkọ́kọ́ tó ṣe pàtàkì. Ọgbọ́n ṣe pàtàkì nínú ìrìnàjò ìgbàgbọ́ wá, kì í ṣe àfikún sí àlàkalẹ̀ wa.

Ọgbọ́n nílò òye. Jòhánù 8:32 sọ wí pé, Ẹ̀yin yóò mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira. " Mímọ òtítọ́ máa ń mú wa gbọ́n àti pẹ̀lú ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn tàkúté èṣù

Ọ̀nààkọ́kọ́ láti níọgbọ́n ni nípasẹ̀ìwé mímọ́, ọ̀rọ̀Ọlọ́run. Jòhánù 1:1 sọ wí pé" Níàtètè kọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lúỌlọ́run, Ọlọ́run sì ni ọ̀rọ̀ náà". Kíkọ́ẹ̀kọ́ọ̀rọ̀Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti níòye Krístì, títọ́ wa sọ́nàọgbọ́n àti ìgbé ayé tó dọ́gba.

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

ỌGBỌ́N

Kìí ṣe pé ìgbé ayé onígbàgbọ́ ní ọ̀nà kan pàtó tí ó ń gbà ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ó ti gba Krístì. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ ti Krístì, a ṣì wà nínú ayé yìí (Jòhánù 17:16). ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àlàkalẹ̀ nílò ìmúyàtọ̀ tí ó mú ìdọ́gba bá wíwà wa lójúkorojú nínú ayé pẹ̀lú ìdámọ̀ wa nípa ẹ̀mí. Bíi ẹ̀dá ti ẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ ṣe bó ti tọ́.

More

A yoo fẹ lati dupẹ lọwọ Mount Zion Faith Ministry fun ipese eto yii. Fun alaye diẹ sii, jọwọ ṣabẹwo: https://mountzionfilm.org/