Gbígbẹ́ Ayé Ọ̀tun: Ní Ọdún TuntunÀpẹrẹ

Wọ Inú Ọdún Tuntun Pẹ̀lú Ìdúpẹ́
Báwo ni o ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun? Tí ọdún tí ó kọjá bá nira tàbí kún fún ìjákulẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ènìyàn fẹ́ sọ pé ó dìgbà sí ọdun ọ̀hún àti pé kí ọdún ọ̀hún máa bá tirẹ̀ lọ láì bojú wo ẹ̀hìn. Ṣùgbọ́n kí o tó pa ìwé ọdún tí ó kọjá dé, ronú sí fífi àsìkò sílẹ̀ láti ro àròjinlẹ́ kí o sì dúpẹ́.
Orin Dáfídì 100 gbà wá ní ìyànjú pé kí á wọ ẹnu ọ̀nà Ọlọ́run pẹ̀lú ọpẹ́ àti àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn— kì í ṣe nítorí pé ipò tí a wà dára, ṣùgbọ́n nítorí pé Ó dará. Kò sí ọ̀nà tí ó dára láti bẹ̀rẹ̀ ọdún náa ju kí á dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ẹni tí Ó jẹ́ àti fún gbogbo nnkan tí ó ti ṣe fún wa.
Dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ilé rẹ, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ, tàbí iṣẹ́ tí o fẹ́ràn. Sọ fún Un pé o dúpẹ́ fún afẹ́fẹ́ tí ò ń mí, ìlera rẹ tí ó dára, tàbi ẹbí tí ó máa ń gbé ọkàn rẹ gbóná. Sọ fún Un pé Ó ṣeun fún ìtọ́sọ́nà àti ìwúrí tí ó fún ọ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nínú Bíbélì. Dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ̀ pé Ó fi ọmọ Rẹ̀ Jésù ránṣẹ́ sí ayé láti kú ikú tí kò tọ́ sí I kí ó lè fún ọ ní ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun tí ìwọ kò lè ṣe iṣẹ́ fún tàbí jẹ ní ogún láéláé.
Ní ìgbà tí a bá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, à ń mọ́ rírì agbára Rẹ̀, wíwà Rẹ́, àti ìpèsè Rẹ̀ nínú ayé wa. Èyí á yí ọ̀nà tí a fi ń wòye Rẹ̀ padà, á sì yí ọ̀nà tí a fi ń rí ipò wa padà. Ní ìgbà tí nnkan bá le pàápàá, kò ṣeé ṣe láti jókòó kí o máa lúwẹ̀ nínú gbogbo àìdára ní ìgbà tí o bá ń yin Ọlọ́run. Fífi ọpẹ́ fún Ọlọ́run máa ń kàn án nípá fún wa láti kọ ẹ̀hìn sí ìrora ọkàn wa kí á sì gbé ojú sókè sí I. Ní ìgbà tí a bá tẹjú mọ Ọn, gbogbo nnkan tí a lè rí ni títóbi Rẹ̀, á sì rán wa létí pé kò sí ọ̀kan kan nínú ìṣòro wa tí ó tóbi jù lọ fún Ọlọ́run wa alágbára.
Nípa kíkọ́kọ́ yin Ọlọ́run, a yí bí a ṣe ń tọ Ọlọ́run lọ padà. Dídúpẹ́ fun ohun tí a ní kí á tó bèèrè fún nnkan mìíràn gbà wá láàyè láti mú ọkàn wa ṣe déédé pẹ̀lú ti Rẹ̀. Ó ràn wá lọ́wọ́ láti wà ní ipò ìrẹ̀lẹ̀, á sì mú èrò wa kúrò nínú pé a ní ẹ̀tọ́ tí ó fi jẹ́ pé bí a kò bá rí ohun tí a bèèrè gbà, a máa rán wa létí ìwà Rẹ̀, ìlérí Rẹ̀, àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa.
Bíbẹ̀rẹ̀ àdúrà pẹ̀lú dídúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run jẹ́ ọ̀nà ìtẹríba kan. Ó jẹ́ ìjẹ́wọ́ láti ọkàn wa pé kìí ṣe nípa tiwa, ṣùgbọ́n gbogbo nnkan jẹ́ nípa Rẹ̀. Ó máa ń yí àfojúsùn wá sí Ọ̀run, á sì mú kí ìfẹ́ wa sí Ọlọ́run jin lẹ̀ si.
Ya àsìkò sí ọ̀tọ̀ láti gba ọ̀nà ọpẹ́ wo ọdún tí ó kọjá. Sọ fún Ọlọ́run nnkan kan tí o dúpẹ́ fún lónìí, bí kò tilẹ̀ ju nnkan kékeré lọ. Bóyá o tilẹ̀ lè pinnu láti máa ṣe é ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tàbí ní ojoojúmọ́. Ṣe àkójọ wọn sínú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ, bẹ̀rẹ̀ ìwé àkọsílẹ̀ ọpẹ́, tàbi kí o pín in lórí àwọn ìkànnì ìbánidọ́rẹ̀ẹ̀ kí ó lé rọrùn fún ọ láti máa dá ìdúróṣinṣin Rẹ̀ mọ̀ nínú ọdún tuntun.
Nípa Ìpèsè yìí

Ọdún Tuntun kọ̀ọ̀kan máa ń fún ni ní àǹfàní tuntun láti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀tun. Má ṣe jẹ́ kí ọdún yìí rí bíi ti àtẹ̀yìnwá pẹ̀lú àwọn ìpinnu tí o kò ní mú ṣẹ. Ètò ọlọ́jọ́ mẹ́rin yìí yóò ràn ọ́ l'ọ́wọ́ láti ronú jinlẹ̀ yóò sì fún ọ ní ìwòye tuntun kí o baà lè sọ ọdún yìí di ọdún tí ó dára jù lọ fún ọ.
More