Àdúrà OlúwaÀpẹrẹ

The Lord's Prayer

Ọjọ́ 6 nínú 8

Ìdáríjì


Ohun àkọ́kọ́ ní pàtàkì: gbèsè níhìn-ín, ó túmọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn onígbèsè àwọn tí ó ti ṣe àìṣòdodo sí wa. Sùgbọ́n nítorí pé a ti mọ iyì bí owó ṣe ń wọlé tàbí bí ó ṣe ń jáde ní ojoojúmọ́, ìmò náà á ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye rẹ̀. Ẹ̀sẹ̀ jẹ gbèsè.

Àwọn nǹkan pàtàkì mẹ́ta kan wà tí a kò gbọ́dọ̀ fi ojú fò dá níhìn-ín.

Ní àkọ́kọ́, Bíbélì jẹ́ kí ó ṣe kedere pé gbogbo wa ni a nílò ìdáríjì pátápátá. Àwọn kan kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí nǹkan pàtàkì, bíi ẹni pé ọ̀ràn kékeré kan ni, tí ó dà bíi ekuru kékeré tí ó wà ní ara aṣọ, tí ènìyàn lè tètè yọ kúrò ní ara rẹ̀. Ó ṣ'eni ní àánú pé àwòrán ẹ̀ṣẹ̀ wa tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ gbòòrò, ó jinlẹ̀, ó sì dé ibi gbogbo.

  • Ẹ̀ṣẹ̀ gbòòrò ju bí a ṣe rò lọ. A sábà máa ń ka ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn nǹkan tí ó máa ń wà ní àkọọ́lẹ̀ nínú ìwé ìròyìn, bíi wòbìà, ìwà ìbàjẹ́ tí ó gba òde kan, panṣágà àti ìpànìyàn. A tún máa ń ka àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú jáì sí àwọn ohun tí kò jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tiwa. Ìtumọ̀ tí Bíbélì fún ẹ̀ṣẹ̀ gbòòrò gan-an, ó sì kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ́ àṣírí, tí kì í fi bẹ́ẹ̀ gba àfiyèsí àwọn ènìyàn: owú jíjẹ, ìwà ọ̀dàlẹ̀, àìní ọ̀wọ̀, èké, ìgbéraga, ìwà ojo, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kódà, Jésù jẹ́ kí a mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe ohun tí ènìyàn ṣe, àmọ́ èrò tí èńìyàn ní.
  • Bákan náà ni ẹ̀ṣẹ̀ jinlẹ̀ ju bí a ṣe rò lọ. Ó jẹ́ àìsàn líle koko, tí kì í lọ bọ̀rọ̀, tí ó ti wọ inú gbogbo apá ìgbésí ayé ẹ̀dá ènìyàn: ara, èrò inú, àti ẹ̀mí. Ohun tí ó tiẹ̀ tún ń kó ìdààmú bá eni jù ni pé ẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní àárín ẹni méjì, ó tún wà ní àárín àwa àti Ọlọ́run.
  • Ẹ̀ṣẹ̀ tún jẹ́ ìṣòro gbogbo àgbáyé ju bí a ṣe rò lọ. Kò sí eni tí ó bọ́ ní ọwọ́ rẹ̀. Èyí ni ohun tí Bíbélì kò kàn sọ fún wa nípa rẹ̀; ó fi hàn nínú Kristi. Nínú ìgbésí ayé rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú àwọn ìwé ìhìn rere, a rí i pé a gbé ìlànà ìjẹ́pípé kan kalẹ̀ ní iwájú wa tí kò sí èyíkéyìí nínú wa tí ó lè mú u ṣẹ.

Èkejì, ìdáríjì ṣeé ṣe. Ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó burú jù lọ tí ìsìn èyíkéyìí tàbí ètò ìgbàgbọ́ èyíkéyìí lè ṣe ni pé kí wọ́n sọ pé àwọn ènìyàn ti da ẹ́ṣẹ̀ láì jẹ́ pé wọ́n ń sọ pé wọ́n ti dárí ji ẹni. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ dà bíi ìgbà tí dókítà kan sọ fún ẹ pé o ní àìsàn líle koko kan àmọ́ tí kò fún ẹ ní ìtọ́jú kankan. Irú Ọlọ́run tí ó máa ń dárí ji ẹni ni ayọ̀ tí ẹ̀sìn Kristẹni dá lé lórí; òun ni ó lè dárí gbèsè wa jì wá. Ìlànà Májẹ̀mú Láíláí dá lórí èrò ti ẹbọ ẹranko tí ó mú ẹ̀ṣẹ̀ onígbàgbọ́ kúrò. Májẹ̀mú Tuntun ṣe àlàyé pé àwọn ẹbọ wọ̀nyẹn ń tọ́ka sí ẹbọ tí Jésù fi ara rẹ̀ rú lórí àgbélébùú. Àyàfi tí a bá jẹ́ kí Ọlọ́run san gbèsè wa nìkan ni a fi lè san án. A lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà; a lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ Kristi.

Ẹ̀kẹta, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdáríjì ọ̀fẹ́ yìí jẹ́ ìhìn rere tí ó dára jù lọ, síbẹ̀ ó ní ojúṣe kan pẹ̀lú. Àwọn tí a dárí jì gbọ́dọ̀ dárí ji ẹlòmíràn. Èyí bá ọgbọ́n mu; bí a bá ti fún wa ní oògùn ìdáríjì láti wo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sàn, ní ìgbà náà a kò lè ṣàì má fún àwọn tí ó ti ṣẹ̀ wá. Àwọn ènìyàn sábà máa ń ṣi ìlànà yìí lò dé ibi pé wọ́n máa ń rò pé bí àwa náà bá kọ́kọ́ dárí ji ẹni ni Ọlọ́run á ṣe dárí jì wá. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, Ọlọ́run ní ó máa ń kọ́kọ́ dárí ji ẹni, ó sì máa ń dárí ji ẹni fàlàlà; àmọ́ èrò kan wà tí ó sọ pé, bí a bá ti dárí jì wá, ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni pé kí a máa dárí ji àwọn ẹlòmíràn. Ìsopọ̀ tí kò ṣeé já ni ó wà ní àárín kí énìyàn dárí jì àti kí a dáríjì wá. Má ṣe jẹ́ kí ó sú ẹ!

Mi ò rò pé ó rọrùn láti dárí jì. Ó rọrùn láti sọ nípa ìwà òǹrorò tàbí ìwà ọ̀dàlẹ̀ kan pé 'a ti dárí rẹ̀ jì ọ́.' Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn ọgbẹ́ kan wà tí ó máa ń jinlẹ̀ dé'bi pé ó lè gba àkókò àti ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ kí wọ́n tó lè jinná.

Ó tún yẹ kí rántí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti dárí jì wá lórí àgbélébùú, a ní láti máa wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní ìgbà gbogbo láti rí ìdáríjì gbà. Àjọṣe tuntun tí a ní pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi òbí pípé wa ń béèrè pé kí á jẹ́ kí ó ṣe kedere sí i nípa ohun tí a ti ṣe tí kò dára ní ìgbà tí a bá bá a pàdé. Ẹ̀ṣẹ̀ tí a kò jẹ́wọ́ rẹ̀, tí a kò sì dárí jì í, yóò di ohun ìdènà ní àárín àwa àti Ọlọ́run, yóò sì ba àjọṣe wa jẹ́. Bí a ṣe ń béèrè fún oúnjẹ òòjọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe yẹ kí a máa béèrè fún ìdáríjì ní ojoojúmọ́.

Nípa Ìpèsè yìí

The Lord's Prayer

Da ara pọ̀ mọ́ J.John l'órí ìkẹ́ẹ̀kọ́ ọjọ́ mẹ́jọ l'órí Àdúrà Olúwa, ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ Jésù tí ó ya'ni l'ẹ́nu tí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ l'órí kíkọ́ni bí ó ṣe yẹ kí a gba àdúrà.

More

A fé láti dúpe lówó J JOHN fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: https://canonjjohn.com