Fífetí sì Ọlọ́runÀpẹrẹ

Listening To God

Ọjọ́ 7 nínú 7

Bí A Tií Mọ Ọlùsọ́àgùntàn Rere

"Èmi ni Ọlùsọ́àgùntàn rere; mo mọ àwọn àgùntàn mi, àwọn àgùntàn mi sì mọ mí—" Jòhánù 10:14 NIV

Fún ọ láti gbà rò, mo nì ìbéèrè méjì láti bèrè lọ́wọ́ rẹ.

Báwo ló tiírí nígbà tí ìwọ bá ń lo àkókò ìjíròrò rẹ pẹ̀lú Bàbá rẹ ní ọ̀run?
Báwo ni ìjíròrò pẹ̀lú Rẹ̀ ti rí?

Ní ìṣẹ́jú díẹ̀ gbìyànjú láti ṣe àpèjúwe àwọn ìrírí yìí.

Ohun tí mòó ń gbìyànjú láti ṣòro rẹ ni Àdúrà. Mo lérò wípé ọ̀pọ̀ ènìyàn a máa lo ọ̀rọ̀ yìí (àdúrà) lódì. A máa ń ṣe akata-kítí nínú àmúlò rẹ̀. Soríi, Olúwa mọ̀ wípé ènìyàn lásán ni àwá, síbẹ̀, a máa ń gbìyànjú láti wúu lórí pẹ̀lú àdúrà àtinúdá. Lẹ́yìn èyí, a ó ní ìdíwọ́ pẹ̀lú ìdádúró títí di ìgbà míràn tí a ó gbìyànjú. Nípa ṣíṣe èyí, a ti kùnọ̀ láti mọ ohun tí àdúrà jẹ́!

Àdúrà jẹ́ ọ̀nà tí a fií ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa. Ó jẹ́ ọ̀nà ìbárẹ́ pẹ̀lúu rẹ. Báwo wá ni Olúwa ti fẹ́ kí a tọ òhun wá nínú àdúrà? Èyí tí ó tóbi jù nínú ìfẹ́ rẹ̀ síwa ni làti ní ọkàn àti ipá wa ni ìkápá rẹ̀, bí a ti kà nínú Diutarónómì 6:5, àbí?

Ṣáájú ohun gbogbo, ó fẹ́ kí a gbádùn Òhun; kí a fi Òhun (láìṣe "àdúrà") ṣe àfojúsùn wa.

A ní láti tọ̀ọ́ wá gẹ́lẹ́ bí a ti rí, kí a sì jọ̀wọ́ arawa (pẹ̀lú gbogbo kùdìẹ̀-kudiẹ) fún Bàbáa wá tí ó ní agbára, ògo àti àánú jùlọ. Tí a bá ti ṣe èyí, a ó rí ago agbára, ìmúbọ̀sípò, ọgbọ́n, àlàáfíà, òdodo àti ayọ̀ tó kún àkúnwọ́sílẹ̀ gbà. Ní iwájú Rẹ ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìyè wà. Òhun ni Omi-Ìyè àti Àkàrà-Ìyè.

Nígbàtí a bá ń gbàdúrà, kìí ṣe ọ̀rọ̀ sísọ nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìtẹ́tí lélẹ̀. Gbìyànjú láti gbọ́ àti láti tẹ̀lé ìlànà rẹ̀. Wà pẹ̀lú ìdùnnú, wá pẹ̀lú eré síse, wá pẹ̀lú ìrẹ̀wẹ̀sì, wá pẹ̀lú iyèméjì àti ẹrú rẹ. Wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ láàrín àfonífojì ikú. Fà súnmọ́ ọ̀dọ̀ọ Rẹ̀, kí o sì tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú-ìyè àti ìrètí.

Nísinsìnyí, a ní láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ loòrè-kóòrè, nínú hílàhílo àti làálàá ayé. Bí atí ṣe èyí, a ó bẹ̀rẹ̀ sí í mọ Olùṣọ́àgùntàn wá sii. Àní, a ó mọ̀ọ́ dáradára.

Fún èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, àkókò àdúrà gbònkẹ́lẹ́ mi máa ń dàbí àkókò ìgbafẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi àtàtà. Ìyanu ńlá ló jẹ́. Ǹkan tó dára, àbí? Bí Paul E. Miller ti sọ nínú ìwé rẹ̀ Ìgbé Ayé Àdúrà,“O kò lè mọ Ọlọ́run pẹ̀lú wùrù-wùrù. A kò lè fowó ra ìbárẹ́, ní ṣe la maá ń wáyè fun.”

Mo lérò wípé ọjọ́ méje tí a ti lò sẹ́yìn nínú ètò yìí tí mú ìmọ̀ rẹ jinlẹ̀ si nípa bí a tií tẹ́tí sí Olúwa. Kìí se ohun tí ó rújú bí a ti máa ń rò. Ó rọrùn bíi ká di etí wa s'írọ́, ṣíṣí ọkàn wa, dídákẹ́ jẹ́, kí a sì gba Olùṣọ́àgùntàn rere láyé láti bá wa jíròrò.

Àdúrà mi ni wípé ìwọ yíò ní òye ìjìnlẹ̀ nípa títẹ́ etí sí Olúwa, ní gbogbo ìgbà, làti lè mọ Olùṣọ́àgùntàn rere síwájú si.

Sọ fún Baba: Lónìí, èmi yíò wá ọ tọkàntọkàn, èmi àti gbogbo ipá mìi. N ó bẹ̀rẹ̀ nísinsìnyí, bí mo ti rí, láti tọ̀ọ́ wá bí O tirí. Mo fẹ́ tún bọ̀ mọ̀ Ọ́, kí n sì máa tẹ́tí sì Óò Ọ ní ọjọọjọ́.

Orin ìjọsìn ti òní: Today’s worship song recommendation: “Fọwọ́ Kan Sánmọ̀” tí a tọwọ́ ẹgbẹ́ Hillsong United kọ

Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Listening To God

Amy Groeschel ti kọ ètò bíbélì yìí ní ìrètí pé yóò di ìtẹ́wọ́gbà bíi wípé ó wá tààrà láti ọkàn Ọlọ́run olùfẹ́ wa sí ọkàn rẹ. Àdúrà Òun tìkálára ni wípé yóò kó̩ ọ láti yàgò fún ohùn tí ń tako ni àti láti tani jí sí ìfiyè sí ohùn rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí www.life.church