ÌhùwàsíÀpẹrẹ

Kíni Ìṣesí?
Kí Ọlọrun, tí ó ń fún wa ní ìrọ́jú ati ìwúrí, jẹ́ kí ẹ ní ọkàn kan náà sí ara yín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Kristi Jesu ...Róòmù 15:5 YCE
Ǹjẹ́ o ti ṣe àkíyèsí bí ohun ibi kékeré kan ti ṣe lè ba gbogbo ọjọ́ rẹ jẹ́? Bóyá ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ kò gba ìna s'ára dáadáa kí ojúmọ́ tóó mọ́, tàbí ọ̀gá rẹ l'ẹ́nu iṣẹ́ dá ọ l'ẹ́bi fún àṣìṣe tí kìí ṣe tìrẹ. Tàbí bóyá o kàn jí s'áyé pẹ̀lú ìkanra, o kò sì mọ ìdí rẹ̀. Ohun tí a ó mú ṣe nínú irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí níí ṣe púpọ̀ pẹ̀lú ìṣesí wa.
Ìṣesí wa ni ìdáhùn wa sí ẹnìkan tàbí ohun kan, à sì máa ń ru ú s'ókè látàrí bí a ṣe ń ronú, ohun tí à ń là kọjá, àti ohun tí à ń ṣe.
Kìí sáábà rọrùn láti mọ ohun ti ìṣesí rere jẹ́, pàápàá ní ìgbà tí a bá wà nínú agbami ayé. Nítorínáà báwo ni a ṣe lè mú ìṣesí wa sunwọ̀n síi?
Ní ìṣẹ́jú kan, fi ojú inú wó ìkòkò ẹja. A fún ọ ní ẹja, omi tí ẹja náa ń gbé inú rẹ̀ dọ̀tí. Láì ṣe àníàní, wá à fẹ́ da omi ìdọ̀tí yìí nù kí o fí omi tí ó mọ́ sí i. Ẹ̀wẹ̀, bí ó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí o ṣe nìkan nìyẹn, kò níí pẹ́ tí omi ẹja rẹ́ yíó tún fi dọ̀tí. O tún ní láti fọ inú ìkòkò láti mú gbogbo gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ àti ẹ̀gbin kúrò. Ní ìgbà náà ìwọ yíó wá bu omi tuntun sí inú ìkòkò náà, ìwọ yíó sì dá ẹja rẹ padà sí inú ilé rẹ̀ tí ó dára fún ìlera.
Ní ìgbà míràn ìṣesí wa lè dàbí ìkòkò ẹja. A lè ní láti mú àwọn ọ̀nà ìrònú wa àtijọ́ tí ó mú ìpalára lọ́wọ́ kúrò bí a ṣe ń yí wá padà pẹ̀lú ohun tí Róòmù 15 pè ní "ọkàn Krístì.”
Ní ọ̀sẹ̀ yìí, a ó máa ṣe àgbéyẹ̀wò Ìwe-mímọ́, ìtàn, àti àdúrà tí ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn Krístì tí ó sì ń kọ́ wà bí a ṣe lè tún wà mọ nípa rẹ̀. Óyá, ẹ jẹ́ kí á ṣe bẹ́ẹ̀! A ti pa àṣamọ̀ rẹ̀ pé ìsesí ní ó jà jù nínú ohun gbogbo. O kò lè ṣe ìkàwọ́ tàbí ìdari àwọn ohun tí yíó ṣẹlẹ̀ sí ọ, ṣúgbọ́n o wà ní ìkáwọ́ irú èsì tí o máa fọ̀ sí wọn. Ìṣesí rẹ nìkan ní o lè ṣe ìkàwọ́ rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Bíbélì ṣe àmúlò ọ̀rọ̀ yìí "ọkàn" láti ṣe àkàwé ohun tí a kàn máa ń pè ní ìṣesí. Ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, èrò inú rẹ wà nínú ìṣe rẹ, ìṣe rẹ a sì máa y'ọri sí àṣà. Àwọn àṣà rẹ ní yíó mọ ìwà rẹ, ìwà rẹ ni yíó sì mọ ọjọ́ iwàjú rẹ. Gbogbo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìṣesí àti ọkàn rẹ. Kíni Bíbélì sọ nípa ìṣesí rẹ?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Báwo ní a ṣe lè hu ìwà tí ó yẹ nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀? Kí gan-an ni ìwà tí ó yẹ? Ètò Bíbélì ọlọ́jọ́-méje yìí wá ìdáhùn jáde nínú ìgbé-ayé àti ẹ̀kọ́ Krístì. Jẹ́ kí àwọn ìsítí ojoojúmọ́ yìí, àwọn àṣàrò àdúrà, àti àwọn ésẹ Ìwé-mímọ́ alágbára ṣe ẹ̀dà ọkàn Krístì ní inú rẹ.
More