Sef 3:9-20

Sef 3:9-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nitori nigbana li emi o yi ède mimọ́ si awọn enia, ki gbogbo wọn ki o le ma pè orukọ Oluwa, lati fi ọkàn kan sìn i. Lati oke odò Etiopia awọn ẹlẹbẹ̀ mi, ani ọmọbinrin afunká mi, yio mu ọrẹ mi wá. Li ọjọ na ni iwọ kì yio tijú, nitori gbogbo iṣe rẹ, ninu eyiti iwọ ti dẹṣẹ si mi: nitori nigbana li emi o mu awọn ti nyọ̀ ninu igberaga rẹ kuro lãrin rẹ, iwọ kì yio si gberaga mọ li oke mimọ́ mi. Emi o fi awọn otòṣi ati talakà enia silẹ pẹlu lãrin rẹ, nwọn o si gbẹkẹ̀le orukọ Oluwa. Awọn iyokù Israeli kì yio hùwa ibi, bẹ̃ni nwọn kì yio sọ̀rọ eke, bẹ̃ni a kì yio ri ahọn arekerekè li ẹnu wọn: ṣugbọn nwọn o jẹun nwọn o si dubulẹ, ẹnikan kì yio si dẹ̀ruba wọn. Kọrin, iwọ ọmọbinrin Sioni; kigbe, iwọ Israeli; fi gbogbo ọkàn yọ̀, ki inu rẹ ki o si dùn, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu. Oluwa ti mu idajọ rẹ wọnni kuro, o ti tì ọta rẹ jade: ọba Israeli, ani Oluwa, mbẹ lãrin rẹ: iwọ kì yio si ri ibi mọ. Li ọjọ na a o wi fun Jerusalemu pe, Iwọ má bẹ̀ru: ati fun Sioni pe, Má jẹ ki ọwọ́ rẹ ki o dẹ̀. Oluwa Ọlọrun rẹ li agbara li ãrin rẹ; yio gbà ni là, yio yọ̀ li ori rẹ fun ayọ̀; yio simi ninu ifẹ rẹ̀, yio fi orin yọ̀ li ori rẹ. Emi o kó awọn ti o banujẹ fun ajọ mimọ́ jọ awọn ti o jẹ tirẹ, fun awọn ti ẹgàn rẹ̀ jasi ẹrù. Kiyesi i, nigbana li emi o ṣe awọn ti npọn ọ li oju: emi a gbà atiro là, emi o si ṣà ẹniti a le jade jọ; emi o si sọ wọn di ẹni iyìn ati olokìki ni gbogbo ilẹ ti a ti gàn wọn. Nigbana li emi o mu nyin padà wá, ani li akokò na li emi o ṣà nyin jọ: nitori emi o fi orukọ ati iyìn fun nyin lãrin gbogbo enia agbaiye, nigbati emi o yi igbèkun nyin padà li oju nyin, ni Oluwa wi.

Sef 3:9-20 Yoruba Bible (YCE)

“N óo wá yí ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pada nígbà náà, yóo sì di mímọ́, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ èmi OLUWA, kí wọ́n sì sìn mí pẹlu ọkàn kan. Láti ọ̀nà jíjìn, níkọjá àwọn odò Etiopia, àwọn ọmọbinrin àwọn eniyan mi tí a fọ́n káàkiri yóo mú ọrẹ ẹbọ wá fún mi. “Ní ọjọ́ náà, a kò ní dójútì yín nítorí ohun tí ẹ ṣe, tí ẹ dìtẹ̀ mọ́ mi; nítorí pé n óo yọ àwọn onigbeeraga kúrò láàrin yín, ẹ kò sì ní ṣoríkunkun sí mi mọ́ ní òkè mímọ́ mi. Nítorí pé, n óo fi àwọn onírẹ̀lẹ̀ ati aláìlera sílẹ̀ sí ààrin yín, orúkọ èmi OLUWA ni wọn yóo gbẹ́kẹ̀lé. Àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli kò ní hùwà burúkú mọ́, wọn kò ní purọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì ní bá ẹ̀tàn lẹ́nu wọn mọ́. Wọn yóo jẹ àjẹyó, wọn yóo dùbúlẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo dẹ́rùbà wọ́n.” Ẹ kọrin sókè, kí ẹ sì hó; ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Ẹ máa yọ̀ kí inú yín sì dùn gidigidi, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! OLUWA ti mú ẹ̀bi yín kúrò, ó sì ti lé àwọn ọ̀tá yín lọ. OLUWA, ọba Israẹli wà lọ́dọ̀ yín; ẹ kò sì ní bẹ̀rù ibi mọ́. Ní ọjọ́ náà, a óo sọ fún Jerusalẹmu pé: “Ẹ má ṣe fòyà; ẹ má sì ṣe jẹ́ kí agbára yín dínkù. OLUWA Ọlọrun yín wà lọ́dọ̀ yín, akọni tí ń fúnni ní ìṣẹ́gun ni; yóo láyọ̀ nítorí yín, yóo tún yín ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ si yín, yóo yọ̀, yóo sì kọrin ayọ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àjọ̀dún.” OLUWA ní: “N óo mú ibi kúrò lórí yín, kí ojú má baà tì yín. N óo wá kọlu àwọn ọ̀tá yín, n óo gba àwọn arọ là, n óo sì kó àwọn tí a ti fọ́nká jọ. N óo yí ìtìjú wọn pada sí ògo gbogbo aráyé ni yóo máa bu ọlá fún wọn. N óo wá mu yín pada wálé nígbà náà, nígbà tí mo bá ko yín jọ tán: n óo sọ yín di eniyan pataki ati ẹni iyì láàrin gbogbo ayé, nígbà tí mo bá dá ire yín pada lójú yín, Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.”

Sef 3:9-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́, nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ OLúWA, láti fi ọkàn kan sìn ín. Láti òkè odò Etiopia, àwọn olùjọsìn mi, àwọn ènìyàn mi tí ó ti fọ́nká, yóò mú ọrẹ wá fún mi. Ní ọjọ́ náà ni a kì yóò sì dójútì nítorí gbogbo iṣẹ́ ibi ni tí ó ti ṣẹ̀ sí mi, nígbà náà ni èmi yóò mu kúrò nínú ìlú yìí, àwọn tí ń yọ̀ nínú ìgbéraga wọn. Ìwọ kì yóò sì gbéraga mọ́ ní òkè mímọ́ mi. Ṣùgbọ́n Èmi yóò fi àwọn ọlọ́kàn tútù àti onírẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ni àárín rẹ̀, wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé orúkọ OLúWA. Àwọn ìyókù Israẹli kì yóò hùwà ibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè ní ẹnu wọn. Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rùbà wọ́n.” Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, kígbe sókè, ìwọ Israẹli! Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu. OLúWA ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn. OLúWA, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ, Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́. Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé, “Má ṣe bẹ̀rù Sioni; má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀. OLúWA Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.” “Èmi ó kó àwọn tí ó ń banújẹ́ fún àjọ̀dún tí a yàn jọ, àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀; àwọn tí ẹ̀gàn rẹ̀ jásí ẹ̀rù. Ní àkókò náà ni èmi yóò dojúkọ àwọn tí ń ni yín lára, èmi yóò gba àtiro là, èmi yóò sì ṣa àwọn tí ó ti fọ́nká jọ, èmi yóò fi ìyìn àti ọlá fún wọn ní gbogbo ilẹ̀ tí a bá ti dójútì wọ́n. Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ; Nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé. Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yín láàrín gbogbo ènìyàn àgbáyé, nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yín padà bọ sípò ní ojú ara yín,” ni OLúWA wí.