Sef 3:14-17
Sef 3:14-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kọrin, iwọ ọmọbinrin Sioni; kigbe, iwọ Israeli; fi gbogbo ọkàn yọ̀, ki inu rẹ ki o si dùn, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu. Oluwa ti mu idajọ rẹ wọnni kuro, o ti tì ọta rẹ jade: ọba Israeli, ani Oluwa, mbẹ lãrin rẹ: iwọ kì yio si ri ibi mọ. Li ọjọ na a o wi fun Jerusalemu pe, Iwọ má bẹ̀ru: ati fun Sioni pe, Má jẹ ki ọwọ́ rẹ ki o dẹ̀. Oluwa Ọlọrun rẹ li agbara li ãrin rẹ; yio gbà ni là, yio yọ̀ li ori rẹ fun ayọ̀; yio simi ninu ifẹ rẹ̀, yio fi orin yọ̀ li ori rẹ.
Sef 3:14-17 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ kọrin sókè, kí ẹ sì hó; ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Ẹ máa yọ̀ kí inú yín sì dùn gidigidi, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! OLUWA ti mú ẹ̀bi yín kúrò, ó sì ti lé àwọn ọ̀tá yín lọ. OLUWA, ọba Israẹli wà lọ́dọ̀ yín; ẹ kò sì ní bẹ̀rù ibi mọ́. Ní ọjọ́ náà, a óo sọ fún Jerusalẹmu pé: “Ẹ má ṣe fòyà; ẹ má sì ṣe jẹ́ kí agbára yín dínkù. OLUWA Ọlọrun yín wà lọ́dọ̀ yín, akọni tí ń fúnni ní ìṣẹ́gun ni; yóo láyọ̀ nítorí yín, yóo tún yín ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ si yín, yóo yọ̀, yóo sì kọrin ayọ̀ sókè
Sef 3:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, kígbe sókè, ìwọ Israẹli! Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu. OLúWA ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nì kúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀tá rẹ padà sẹ́yìn. OLúWA, ọba Israẹli wà pẹ̀lú rẹ, Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́. Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé, “Má ṣe bẹ̀rù Sioni; má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀. OLúWA Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, Ó ní agbára láti gbà ọ là. Yóò yọ̀ ni orí rẹ fún ayọ̀; Yóò tún ọ ṣe nínú ìfẹ́ rẹ̀, Yóò sì fi orin yọ̀ ní orí rẹ.”