Rut 1:20-21
Rut 1:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
On si wi fun wọn pe, Ẹ má pè mi ni Naomi mọ́, ẹ mã pè mi ni Mara: nitoriti Olodumare hùwa kikorò si mi gidigidi. Mo jade lọ ni kikún, OLUWA si tun mú mi pada bọ̀wá ile li ofo: ẽhaṣe ti ẹnyin fi npè mi ni Naomi, nigbati OLUWA ti jẹritì mi, Olodumare si ti pọn mi loju?
Rut 1:20-21 Yoruba Bible (YCE)
Naomi bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ má pè mí ní Naomi mọ́, Mara ni kí ẹ máa pè mí nítorí pé Olodumare ti jẹ́ kí ayé korò fún mi. Mo jáde lọ ní kíkún, ṣugbọn OLUWA ti mú mi pada ní ọwọ́ òfo, kí ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Naomi, nígbà tí OLUWA fúnra rẹ̀ ti dá mi lẹ́bi, tí Olodumare sì ti mú ìpọ́njú bá mi?”
Rut 1:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Naomi sì dáhùn wí pé, “Ẹ má ṣe pè mí ní Naomi. Ẹ pè mí ní Mara (Ìkorò), nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò. Mo jáde ní kíkún, ṣùgbọ́n OLúWA mú mi padà ní òfo. Nítorí náà kín ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Naomi, nígbà tí Olódùmarè ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí ó sì mú ìdààmú bá mi?”