Rut 1

1
Elimeleki ati Idile rẹ̀ lọ lati máa gbe ni Moabu
1O si ṣe li ọjọ́ wọnni ti awọn onidajọ nṣe olori, ìyan kan si mu ni ilẹ na. Ọkunrin kan lati Betilehemu-juda si lọ ṣe atipo ni ilẹ Moabu, on, ati obinrin rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin meji.
2Orukọ ọkunrin na a si ma jẹ́ Elimeleki, orukọ obinrin rẹ̀ a si ma jẹ́ Naomi, orukọ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji a si ma jẹ́ Maloni ati Kilioni, awọn ara Efrata ti Betilehemu-juda. Nwọn si wá si ilẹ Moabu, nwọn si ngbé ibẹ̀.
3Elimeleki ọkọ Naomi si kú; o si kù on, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji.
4Nwọn si fẹ́ aya ninu awọn obinrin Moabu; orukọ ọkan a ma jẹ́ Orpa, orukọ ekeji a si ma jẹ́ Rutu: nwọn si wà nibẹ̀ nìwọn ọdún mẹwa.
5Awọn mejeji, Maloni ati Kilioni, si kú pẹlu; obinrin na li o si kù ninu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji ati ọkọ rẹ̀.
Náómì àti Rutu Padà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
6Nigbana li o dide pẹlu awọn aya-ọmọ rẹ̀, ki o le pada lati ilẹ Moabu wá: nitoripe o ti gbọ́ ni ilẹ Moabu bi OLUWA ti bẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò ni fifi onjẹ fun wọn.
7O si jade kuro ni ibi ti o gbé ti wà, ati awọn aya-ọmọ rẹ̀ mejeji pẹlu rẹ̀; nwọn si mu ọ̀na pọ̀n lati pada wá si ilẹ Juda.
8Naomi si wi fun awọn aya-ọmọ rẹ̀ mejeji pe, Ẹ lọ, ki olukuluku pada lọ si ile iya rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe rere fun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin ti ṣe fun awọn okú, ati fun mi.
9Ki OLUWA ki o fi fun nyin ki ẹnyin le ri isimi, olukuluku nyin ni ile ọkọ rẹ̀. Nigbana li o fi ẹnu kò wọn lẹnu; nwọn si gbé ohùn wọn soke nwọn si sọkun.
10Nwọn si wi fun u pe, Nitõtọ awa o bá ọ pada lọ sọdọ awọn enia rẹ.
11Naomi si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin mi ẹ pada: ẽṣe ti ẹnyin o fi bá mi lọ? mo ha tun ní ọmọkunrin ni inu mi, ti nwọn iba fi ṣe ọkọ nyin?
12Ẹ pada, ẹnyin ọmọbinrin mi, ẹ ma lọ; nitori emi di arugbo jù ati ní ọkọ. Bi emi wipe, Emi ní ireti, bi emi tilẹ ní ọkọ li alẹ yi, ti emi si bi ọmọkunrin;
13Ẹnyin ha le duro dè wọn titi nwọn o fi dàgba? Ẹnyin o le duro dè wọn li ainí ọkọ? Rara o, ẹnyin ọmọbinrin mi; nitoripe inu mi bàjẹ́ gidigidi nitori nyin, ti ọwọ́ OLUWA fi jade si mi.
14Nwọn si gbé ohùn wọn soke, nwọn si tun sọkun: Orpa si fi ẹnu kò iya-ọkọ rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn Rutu fàmọ́ ọ.
15On si wipe, Kiyesi i, orogun rẹ pada sọdọ awọn enia rẹ̀, ati sọdọ oriṣa rẹ̀: iwọ pada tẹlé orogun rẹ.
16Rutu si wipe, Máṣe rọ̀ mi lati fi ọ silẹ, tabi lati pada kuro lẹhin rẹ: nitori ibiti iwọ ba lọ, li emi o lọ; ibiti iwọ ba si wọ̀, li emi o wọ̀: awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi:
17Ibiti iwọ ba kú li emi o kú si, nibẹ̀ li a o si sin mi: ki OLUWA ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi ohun kan bikoṣe ikú ba yà iwọ ati emi.
18Nigbati on ri pe o ti pinnu rẹ̀ tán lati bá on lọ, nigbana li o dẹkun ọ̀rọ ibá a sọ.
19Bẹ̃ni awọn mejeji lọ titi nwọn fi dé Betilehemu. O si ṣe, ti nwọn dé Betilehemu, gbogbo ilu si dide nitori wọn, nwọn si wipe, Naomi li eyi?
20On si wi fun wọn pe, Ẹ má pè mi ni Naomi mọ́, ẹ mã pè mi ni Mara: nitoriti Olodumare hùwa kikorò si mi gidigidi.
21Mo jade lọ ni kikún, OLUWA si tun mú mi pada bọ̀wá ile li ofo: ẽhaṣe ti ẹnyin fi npè mi ni Naomi, nigbati OLUWA ti jẹritì mi, Olodumare si ti pọn mi loju?
22Bẹ̃ni Naomi padawá, ati Rutu ara Moabu, aya-ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ẹniti o ti ilẹ Moabu wá; nwọn si wá si Beti-lehemu ni ìbẹrẹ ikore ọkà-barle.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Rut 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀