Rut 1:1-22

Rut 1:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe li ọjọ́ wọnni ti awọn onidajọ nṣe olori, ìyan kan si mu ni ilẹ na. Ọkunrin kan lati Betilehemu-juda si lọ ṣe atipo ni ilẹ Moabu, on, ati obinrin rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin meji. Orukọ ọkunrin na a si ma jẹ́ Elimeleki, orukọ obinrin rẹ̀ a si ma jẹ́ Naomi, orukọ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji a si ma jẹ́ Maloni ati Kilioni, awọn ara Efrata ti Betilehemu-juda. Nwọn si wá si ilẹ Moabu, nwọn si ngbé ibẹ̀. Elimeleki ọkọ Naomi si kú; o si kù on, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji. Nwọn si fẹ́ aya ninu awọn obinrin Moabu; orukọ ọkan a ma jẹ́ Orpa, orukọ ekeji a si ma jẹ́ Rutu: nwọn si wà nibẹ̀ nìwọn ọdún mẹwa. Awọn mejeji, Maloni ati Kilioni, si kú pẹlu; obinrin na li o si kù ninu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji ati ọkọ rẹ̀. Nigbana li o dide pẹlu awọn aya-ọmọ rẹ̀, ki o le pada lati ilẹ Moabu wá: nitoripe o ti gbọ́ ni ilẹ Moabu bi OLUWA ti bẹ̀ awọn enia rẹ̀ wò ni fifi onjẹ fun wọn. O si jade kuro ni ibi ti o gbé ti wà, ati awọn aya-ọmọ rẹ̀ mejeji pẹlu rẹ̀; nwọn si mu ọ̀na pọ̀n lati pada wá si ilẹ Juda. Naomi si wi fun awọn aya-ọmọ rẹ̀ mejeji pe, Ẹ lọ, ki olukuluku pada lọ si ile iya rẹ̀: ki OLUWA ki o ṣe rere fun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin ti ṣe fun awọn okú, ati fun mi. Ki OLUWA ki o fi fun nyin ki ẹnyin le ri isimi, olukuluku nyin ni ile ọkọ rẹ̀. Nigbana li o fi ẹnu kò wọn lẹnu; nwọn si gbé ohùn wọn soke nwọn si sọkun. Nwọn si wi fun u pe, Nitõtọ awa o bá ọ pada lọ sọdọ awọn enia rẹ. Naomi si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin mi ẹ pada: ẽṣe ti ẹnyin o fi bá mi lọ? mo ha tun ní ọmọkunrin ni inu mi, ti nwọn iba fi ṣe ọkọ nyin? Ẹ pada, ẹnyin ọmọbinrin mi, ẹ ma lọ; nitori emi di arugbo jù ati ní ọkọ. Bi emi wipe, Emi ní ireti, bi emi tilẹ ní ọkọ li alẹ yi, ti emi si bi ọmọkunrin; Ẹnyin ha le duro dè wọn titi nwọn o fi dàgba? Ẹnyin o le duro dè wọn li ainí ọkọ? Rara o, ẹnyin ọmọbinrin mi; nitoripe inu mi bàjẹ́ gidigidi nitori nyin, ti ọwọ́ OLUWA fi jade si mi. Nwọn si gbé ohùn wọn soke, nwọn si tun sọkun: Orpa si fi ẹnu kò iya-ọkọ rẹ̀ lẹnu; ṣugbọn Rutu fàmọ́ ọ. On si wipe, Kiyesi i, orogun rẹ pada sọdọ awọn enia rẹ̀, ati sọdọ oriṣa rẹ̀: iwọ pada tẹlé orogun rẹ. Rutu si wipe, Máṣe rọ̀ mi lati fi ọ silẹ, tabi lati pada kuro lẹhin rẹ: nitori ibiti iwọ ba lọ, li emi o lọ; ibiti iwọ ba si wọ̀, li emi o wọ̀: awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi: Ibiti iwọ ba kú li emi o kú si, nibẹ̀ li a o si sin mi: ki OLUWA ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi ohun kan bikoṣe ikú ba yà iwọ ati emi. Nigbati on ri pe o ti pinnu rẹ̀ tán lati bá on lọ, nigbana li o dẹkun ọ̀rọ ibá a sọ. Bẹ̃ni awọn mejeji lọ titi nwọn fi dé Betilehemu. O si ṣe, ti nwọn dé Betilehemu, gbogbo ilu si dide nitori wọn, nwọn si wipe, Naomi li eyi? On si wi fun wọn pe, Ẹ má pè mi ni Naomi mọ́, ẹ mã pè mi ni Mara: nitoriti Olodumare hùwa kikorò si mi gidigidi. Mo jade lọ ni kikún, OLUWA si tun mú mi pada bọ̀wá ile li ofo: ẽhaṣe ti ẹnyin fi npè mi ni Naomi, nigbati OLUWA ti jẹritì mi, Olodumare si ti pọn mi loju? Bẹ̃ni Naomi padawá, ati Rutu ara Moabu, aya-ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ẹniti o ti ilẹ Moabu wá; nwọn si wá si Beti-lehemu ni ìbẹrẹ ikore ọkà-barle.

Rut 1:1-22 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò tí àwọn adájọ́ ń ṣe olórí ní ilẹ̀ Israẹli, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà. Ọkunrin kan wà, ará Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, òun ati aya rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeeji; wọ́n lọ ń gbé ilẹ̀ Moabu. Orúkọ ọkunrin náà ni Elimeleki, aya rẹ̀ ń jẹ́ Naomi, àwọn ọmọkunrin rẹ̀ sì ń jẹ́ Maloni ati Kilioni. Wọ́n kó kúrò ní Efurata ti Bẹtilẹhẹmu, ní ilẹ̀ Juda, wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Moabu, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Nígbà tí ó yá, Elimeleki kú, ó bá ku Naomi, opó rẹ̀, ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ mejeeji. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji fẹ́ aya láàrin àwọn ọmọ Moabu, Iyawo ẹnikinni ń jẹ́ Opa, ti ẹnìkejì sì ń jẹ́ Rutu. Lẹ́yìn nǹkan bíi ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ti jọ ń gbé ilẹ̀ Moabu, Maloni ati Kilioni náà kú, Naomi sì ṣe bẹ́ẹ̀ ṣòfò àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji ati ọkọ rẹ̀. Naomi ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji jáde kúrò ní ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń pada lọ sí ilẹ̀ Juda, nítorí ó gbọ́ pé OLUWA ti ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ati pé wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ. Òun ati àwọn opó àwọn ọmọ rẹ̀ bá gbéra láti ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Juda. Bí wọ́n ti ń lọ, Naomi yíjú pada sí àwọn mejeeji, ó ní, “Ẹ̀yin mejeeji, ẹ pada sí ilé ìyá yín. Kí OLUWA ṣàánú fun yín, bí ẹ ti ṣàánú fún èmi ati àwọn òkú ọ̀run. Kí OLUWA ṣe ilé ọkọ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá tún ní, ní ilé rẹ̀.” Ó bá kí wọn, ó fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, ó dágbére fún wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Wọ́n dáhùn, wọ́n ní, “Rárá o, a óo bá ọ pada lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ.” Naomi dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi. Kí ló dé tí ẹ fẹ́ bá mi lọ? Ọmọ wo ló tún kù ní ara mi tí n óo ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí yóo ṣú yín lópó? Ẹ pada, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ máa bá tiyín lọ. Ogbó ti dé sí mi, n kò tún lè ní ọkọ mọ́. Bí mo bá tilẹ̀ wí pé mo ní ìrètí, tí mo sì ní ọkọ ní alẹ́ òní, tí mo sì bí àwọn ọmọkunrin, ṣé ẹ óo dúró títí wọn óo fi dàgbà ni, àbí ẹ óo sọ pé ẹ kò ní ní ọkọ mọ́? Kò ṣeéṣe, ẹ̀yin ọmọ mi. Ó dùn mí fun yín pé OLUWA ti bá mi jà.” Wọ́n bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún. Nígbà tí ó yá, Opa fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì dágbére fún un; ṣugbọn Rutu kò kúrò lọ́dọ̀ ìyakọ rẹ̀. Naomi bá sọ fún Rutu, ó ní, “Ṣé o rí i pé arabinrin rẹ ti pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ati àwọn oriṣa rẹ̀, ìwọ náà pada, kí ẹ jọ máa lọ.” Ṣugbọn Rutu dáhùn, ó ní, “Má pàrọwà fún mi rárá, pé kí n fi ọ́ sílẹ̀, tabi pé kí n pada lẹ́yìn rẹ; nítorí pé ibi tí o bá ń lọ, ni èmi náà yóo lọ; ibi tí o bá ń gbé ni èmi náà yóo máa gbé; àwọn eniyan rẹ ni yóo máa jẹ́ eniyan mi, Ọlọrun rẹ ni yóo sì jẹ́ Ọlọrun mi. Ibi tí o bá kú sí, ni èmi náà yóo kú sí; níbẹ̀ ni wọn yóo sì sin mí sí pẹlu. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ yìí, kí OLUWA jẹ́ kí ohun tí ó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ bá mi, bí mo bá jẹ́ kí ohunkohun yà mí kúrò lẹ́yìn rẹ, ìbáà tilẹ̀ jẹ́ ikú.” Nígbà tí Naomi rí i pé Rutu ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀ láti bá òun lọ, kò sọ ohunkohun mọ́. Àwọn mejeeji bá bẹ̀rẹ̀ sí lọ títí wọ́n fi dé Bẹtilẹhẹmu. Nígbà tí wọ́n wọ Bẹtilẹhẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì nítorí wọn. Àwọn obinrin bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ṣé Naomi nìyí?” Naomi bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ má pè mí ní Naomi mọ́, Mara ni kí ẹ máa pè mí nítorí pé Olodumare ti jẹ́ kí ayé korò fún mi. Mo jáde lọ ní kíkún, ṣugbọn OLUWA ti mú mi pada ní ọwọ́ òfo, kí ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Naomi, nígbà tí OLUWA fúnra rẹ̀ ti dá mi lẹ́bi, tí Olodumare sì ti mú ìpọ́njú bá mi?” Báyìí ni Naomi ati Rutu, ará Moabu, aya ọmọ rẹ̀, ṣe pada dé láti ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Ní àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà baali ni wọ́n dé sí Bẹtilẹhẹmu.

Rut 1:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ìgbà tí àwọn onídàájọ́ ń ṣe àkóso ilẹ̀ Israẹli, ìyàn kan mú ní ilẹ̀ náà, ọkùnrin kan láti Bẹtilẹhẹmu ti Juda, òun àti aya rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjì lọ láti máa gbé ní ilẹ̀ Moabu fún ìgbà díẹ̀. Orúkọ ọkùnrin náà ń jẹ́ Elimeleki, orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Naomi, orúkọ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì sì ni Maloni àti Kilioni àwọn ará Efrata, ti Bẹtilẹhẹmu ti Juda. Wọ́n sì lọ sí ilẹ̀ Moabu, wọ́n ń gbé níbẹ̀. Ní àsìkò tí wọ́n ń gbé ibẹ̀, Elimeleki, ọkọ Naomi kú, ó sì ku òun pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì. Wọ́n sì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin ará Moabu méjì, orúkọ ọ̀kan ń jẹ́ Oripa, èkejì sì ń jẹ́ Rutu. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti gbé níbẹ̀ fún bí ọdún mẹ́wàá, Maloni àti Kilioni náà sì kú, Naomi sì wà láìsí ọkọ tàbí ọmọ kankan fún un mọ́. Nígbà tí Naomi gbọ́ ní Moabu tí ó wà wí pé OLúWA ti bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò nípa fífún wọn ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ. Ó sì dìde pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì láti padà sí ìlú rẹ̀. Òun pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ rẹ̀ méjèèjì ni wọ́n jọ fi ibi tí ó ń gbé sílẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn padà sí ilẹ̀ Juda. Ṣùgbọ́n ní ojú ọ̀nà, Naomi wí fún àwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì pé, “Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín padà sí ilé ìyá rẹ̀. Kí OLúWA ṣe àánú fún yín bí ẹ ti ṣe sí èmi àti àwọn ọkọ yín tí ó kú. Kí OLúWA kí ó fi yín lọ́kàn balẹ̀ ní ilé ọkọ mìíràn.” Naomi sì fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu wí pé “Ó dìgbà,” Wọ́n sì sọkún kíkankíkan. Wọ́n sì wí fún un pé, “Rárá, a ó bà ọ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.” Ṣùgbọ́n Naomi dáhùn wí pé, “Ẹ padà sílé ẹ̀yin ọmọ mi. Nítorí kí ni ẹ fi fẹ́ wá pẹ̀lú mi? Ṣé mo tún le bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn ni, tí ó le ṣe ọkọ yin? Ẹ padà sílé, ẹ̀yin ọmọ mi, nítorí èmi ti di arúgbó jù láti ní ọkọ mìíràn. Bí èmí wí pé, Èmí ní ìrètí, bí èmí tilẹ̀ ní ọkọ mìíràn ní alẹ́ yìí, tí èmí sì bí àwọn ọmọkùnrin mìíràn, ẹ̀yin ha le è dúró dìgbà tí wọ́n yóò fi dàgbà? Ẹ̀yin ó le è dúró dè wọ́n láì fẹ́ ọkọ mìíràn? Rárá, ẹ̀yin ọmọbìnrin mi, nítorí pé inú mi bàjẹ́ gidigidi ju tiyín lọ, nítorí tí ọwọ́ OLúWA fi jáde sí mi!” Wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì tún sọkún. Nígbà náà ní Oripa fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ ní ẹnu wí pé ó dìgbà, ṣùgbọ́n Rutu dì mọ́ ọn síbẹ̀. Naomi wí pé, “Wò ó, arábìnrin rẹ ti padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti òrìṣà rẹ̀, ìwọ náà padà pẹ̀lú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n Rutu dáhùn wí pé, “Má ṣe rọ̀ mí láti fi ọ́ sílẹ̀ tàbí láti padà lẹ́yìn rẹ. Ibi tí ìwọ bá lọ ní èmi yóò lọ, ibi ti ìwọ bá dúró ni èmi yóò dúró, àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run, mi, Níbi tí ìwọ bá kú sí ni èmi yóò kú sí, níbẹ̀ ni wọn yóò sì sin mí sí. Kí OLúWA jẹ mí ní ìyà tí ó lágbára, bí ohunkóhun bí kò ṣe ikú bá yà wá.” Nígbà tí Naomi rí i wí pé Rutu ti pinnu láti tẹ̀lé òun kò rọ̀ láti padà mọ́. Àwọn méjèèjì sì ń lọ títí wọ́n fi dé ìlú Bẹtilẹhẹmu. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ariwo ìpadàbọ̀ wọn gba ìlú kan, àwọn obìnrin ibẹ̀ sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Naomi ni èyí bí?” Naomi sì dáhùn wí pé, “Ẹ má ṣe pè mí ní Naomi. Ẹ pè mí ní Mara (Ìkorò), nítorí wí pé Olódùmarè ti mú kí ayé mi di kíkorò. Mo jáde ní kíkún, ṣùgbọ́n OLúWA mú mi padà ní òfo. Nítorí náà kín ló dé tí ẹ fi ń pè mí ní Naomi, nígbà tí Olódùmarè ti kọ̀ mí sílẹ̀, tí ó sì mú ìdààmú bá mi?” Báyìí ni Naomi ṣe padà láti Moabu pẹ̀lú Rutu, ará Moabu ìyàwó ọmọ rẹ̀. Wọ́n gúnlẹ̀ sí Bẹtilẹhẹmu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà barle.