Rom 2:6-29
Rom 2:6-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run yóò san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀: Àwọn ẹni tí ń fi sùúrù nínú rere ṣíṣe, wá ògo àti ọlá àti àìdíbàjẹ́ ni yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun fún. Ṣùgbọ́n fún àwọn onímọ̀-tara-ẹni-nìkan, tí wọn kò sì gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọn ń tẹ̀lé ọ̀nà búburú, wọn yóò ní ìrírí ìrunú àti ìbínú rẹ̀. Ìpọ́njú àti ìrora, yóò wà lórí olúkúlùkù ọkàn ènìyàn tí ń hùwà ibi: ti Júù ṣáájú, àti àwọn Helleni pẹ̀lú; ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn Helleni pẹ̀lú: Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin: àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́; Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni ẹni ìdáláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dá láre. Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin. Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí. Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi. Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálòpọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run, tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dára jùlọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin; tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn, Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́, Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí? Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kórìíra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹmpili ní olè bí? Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin? Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́, “Orúkọ Ọlọ́run sá à di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrín àwọn aláìkọlà nítorí yín.” Nítorí ìkọlà ní èrè nítòótọ́, bí ìwọ bá pa òfin mọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ arúfin, ìkọlà rẹ di àìkọlà. Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí a kọ nílà bí? Aláìkọlà nípa àdánidá, bí ó bá pa òfin mọ́, yóò dá ẹ̀bi fún ìwọ tí ó jẹ́ arúfin nípa ti àkọsílẹ̀ òfin àti ìkọlà. Kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní òde ni Júù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní ara ni ìkọlà: Ṣùgbọ́n Júù ti inú ni Júù, àti ìkọlà sì ni ti ọkàn nínú ẹ̀mí tí kì í ṣe ti àkọsílẹ̀, ìyìn ẹni tí kò sí lọ́dọ̀ ènìyàn, bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Rom 2:6-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti yio san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀: Fun awọn ti nfi sũru ni rere-iṣe wá ogo ati ọlá ati aidibajẹ, ìye ainipẹkun; Ṣugbọn fun awọn onijà, ti nwọn kò si gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ngbà aiṣododo gbọ́, irunu ati ibinu yio wà. Ipọnju ati irora, lori olukuluku ọkàn enia ti nhuwa ibi, ti Ju ṣaju, ati ti Hellene pẹlu; Ṣugbọn ogo, ati ọlá, ati alafia, fun olukuluku ẹni ti nhuwa rere, fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu: Nitori ojuṣaju enia kò si lọdọ Ọlọrun. Nitori iye awọn ti o ṣẹ̀ li ailofin, nwọn ó si ṣegbé lailofin: ati iye awọn ti o ṣẹ̀ labẹ ofin, awọn li a o fi ofin dalẹjọ; Nitori kì iṣe awọn olugbọ ofin li alare lọdọ Ọlọrun, ṣugbọn awọn oluṣe ofin li a o dalare. Nitori nigbati awọn Keferi, ti kò li ofin, ba ṣe ohun ti o wà ninu ofin nipa ẹda, awọn wọnyi ti kò li ofin, jẹ ofin fun ara wọn: Awọn ẹniti o fihan pe, a kọwe iṣẹ ofin si wọn li ọkàn, ti ọkàn wọn si njẹ wọn lẹri, ti iro wọn larin ara wọn si nfi wọn sùn tabi ti o ngbè wọn, Li ọjọ na nigbati Ọlọrun yio ti ipa Jesu Kristi ṣe idajọ aṣiri enia gẹgẹ bi ihinrere mi. Ṣugbọn bi a ba npè iwọ ni Ju, ti o si simi le ofin, ti o si nṣogo ninu Ọlọrun, Ti o si mọ̀ ifẹ rẹ̀, ti o si dán ohun ti o yàtọ wò, ẹniti a ti kọ li ofin; Ti o si gbé oju le ara rẹ̀ pe iwọ li amọ̀na awọn afọju, imọlẹ awọn ti o wà li òkunkun, Olukọ awọn alaimoye, olukọ awọn ọmọde, ẹniti o ni afarawe imọ ati otitọ ofin li ọwọ. Njẹ iwọ ti o nkọ́ ẹlomiran, iwọ kò kọ́ ara rẹ? iwọ ti o nwasu ki enia ki o má jale, iwọ njale? Iwọ ti o nwipe ki enia ki o máṣe panṣaga, iwọ nṣe panṣaga? iwọ ti o ṣe họ̃ si oriṣa, iwọ njà tẹmpili li ole? Iwọ ti nṣogo ninu ofin, ni riru ofin iwọ bù Ọlọrun li ọlá kù? Nitori orukọ Ọlọrun sá di isọrọ-buburu si ninu awọn Keferi nitori nyin, gẹgẹ bi a ti kọ ọ. Nitori ikọla li ère lõtọ, bi iwọ ba pa ofin mọ́: ṣugbọn bi iwọ ba jẹ arufin, ikọla rẹ di aikọla. Nitorina bi alaikọla ba pa ilana ofin mọ́, a kì yio ha kà aikọla rẹ̀ si ikọla bi? Alaikọla nipa ti ẹda, bi o ba pa ofin mọ́, kì yio ha da ẹbi fun iwọ ti o jẹ arufin nipa ti iwe ati ikọla? Kì iṣe eyi ti o farahan ni Ju, bẹni kì iṣe eyi ti o farahan li ara ni ikọla: Ṣugbọn Ju ti inu ni Ju, ati ikọla ti ọkàn, ninu ẹmi ni, kì iṣe ti ode ara; iyìn ẹniti kò si lọdọ enia, bikoṣe lọdọ Ọlọrun.
Rom 2:6-29 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun yóo san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀; yóo fi ìyè ainipẹkun fún àwọn tí ń fi sùúrù ṣe iṣẹ́ rere nípa lílépa àwọn nǹkan tí ó lógo, tí ó sì lọ́lá, àwọn nǹkan tí kò lè bàjẹ́. Ṣugbọn ní ti àwọn tí ó jẹ́ pé ti ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, ati àwọn tí kò gba òtítọ́, àwọn tí wọ́n gba ohun burúkú, Ọlọrun yóo fi ibinu ati ìrúnú rẹ̀ hàn wọ́n; yóo mú ìpọ́njú ati ìṣòro bá gbogbo àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ ibi. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ kàn, lẹ́yìn náà àwọn Giriki. Ṣugbọn yóo fi ògo, ọlá ati alaafia fún gbogbo àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ fún, lẹ́yìn náà yóo fún àwọn Giriki. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ láì lófin, láì lófin náà ni wọn yóo kú. Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ Òfin, tí wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀, òfin náà ni a óo fi ṣe ìdájọ́ wọn. Kì í ṣe àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí Òfin sọ ni Ọlọrun ń dá láre, àwọn tí wọn ń ṣe ohun tí Òfin sọ ni. Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu tí kò mọ Òfin bá ń ṣe ohun tí Òfin sọ bí nǹkan àmútọ̀runwá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ Òfin, wọ́n di òfin fún ara wọn. Irú àwọn wọnyi fihàn pé a ti kọ iṣẹ́ ti Òfin sinu ọkàn wọn. Ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ ninu wọn: àwọn èrò oríṣìíríṣìí tí ó wà ninu wọn yóo máa dá wọn láre tabi kí ó máa dá wọn lẹ́bi, ní ọjọ́ tí Ọlọrun yóo rán Jesu láti ṣe ìdájọ́ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo tí ó wà ninu eniyan gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí mò ń waasu. Ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní Juu, o gbójú lé Òfin, o wá ń fọ́nnu pé o mọ Ọlọrun. O mọ ohun tí Ọlọrun fẹ́. O mọ àwọn ohun tí ó dára jù nítorí a ti fi Òfin kọ́ ọ. O dá ara rẹ lójú bí ẹni tí ó jẹ́ amọ̀nà fún àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn. O pe ara rẹ ní ẹni tí ó lè bá àwọn tí kò gbọ́n wí, olùkọ́ àwọn ọ̀dọ́, ẹni tí ó mọ àwọn nǹkan tí ó jẹ́ kókó ati òtítọ́ tí ó wà ninu Òfin. Ìwọ tí ò ń kọ́ ẹlòmíràn, ṣé o kò ní kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ò ń waasu pé kí eniyan má jalè, ṣé ìwọ náà kì í jalè? Ìwọ tí o sọ pé kí eniyan má ṣe àgbèrè, ṣé ìwọ náà kì í ṣe àgbèrè? Ìwọ tí o kórìíra oriṣa, ṣé o kì í ja ilé ìbọ̀rìṣà lólè? Ìwọ tí ò ń fọ́nnu pé o mọ Òfin, ṣé o kì í mú ẹ̀gàn bá Ọlọrun nípa rírú Òfin? Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Orúkọ Ọlọrun di ohun ìṣáátá láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu nítorí yín.” Ilà tí o kọ ní anfaani, bí o bá ń pa Òfin mọ́. Ṣugbọn tí o bá rú Òfin, bí àìkọlà ni ìkọlà rẹ rí. Ǹjẹ́ bí aláìkọlà bá ń pa àwọn ìlànà òdodo tí ó wà ninu Òfin mọ́, a kò ha ní ka àìkọlà rẹ̀ sí ìkọlà? Ẹni tí a bí ní aláìkọlà tí ó ń pa Òfin mọ́, ó mú ìtìjú bá ìwọ tí a kọ Òfin sílẹ̀ fún, tí o kọlà, ṣugbọn sibẹ tí o jẹ́ arúfin. Kì í ṣe nǹkan ti òde ara ni eniyan fi ń jẹ́ Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìkọlà kì í ṣe kí á fabẹ gé ara. Ṣugbọn láti jẹ́ Juu tòótọ́ jẹ́ ohun àtinúwá; ìkọlà jẹ́ nǹkan ti ọkàn. Nǹkan ti ẹ̀mí ni, kì í ṣe ti inú ìwé. Ìyìn irú ẹni bẹ́ẹ̀ wà lọ́dọ̀ Ọlọrun, kì í ṣe ọ̀dọ̀ eniyan.