ROMU 2:6-29

ROMU 2:6-29 YCE

Ọlọrun yóo san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀; yóo fi ìyè ainipẹkun fún àwọn tí ń fi sùúrù ṣe iṣẹ́ rere nípa lílépa àwọn nǹkan tí ó lógo, tí ó sì lọ́lá, àwọn nǹkan tí kò lè bàjẹ́. Ṣugbọn ní ti àwọn tí ó jẹ́ pé ti ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, ati àwọn tí kò gba òtítọ́, àwọn tí wọ́n gba ohun burúkú, Ọlọrun yóo fi ibinu ati ìrúnú rẹ̀ hàn wọ́n; yóo mú ìpọ́njú ati ìṣòro bá gbogbo àwọn tí ó ń ṣe iṣẹ́ ibi. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ kàn, lẹ́yìn náà àwọn Giriki. Ṣugbọn yóo fi ògo, ọlá ati alaafia fún gbogbo àwọn tí ó ń ṣe rere. Àwọn Juu ni yóo kọ́kọ́ fún, lẹ́yìn náà yóo fún àwọn Giriki. Nítorí Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ láì lófin, láì lófin náà ni wọn yóo kú. Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ Òfin, tí wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀, òfin náà ni a óo fi ṣe ìdájọ́ wọn. Kì í ṣe àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí Òfin sọ ni Ọlọrun ń dá láre, àwọn tí wọn ń ṣe ohun tí Òfin sọ ni. Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu tí kò mọ Òfin bá ń ṣe ohun tí Òfin sọ bí nǹkan àmútọ̀runwá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ Òfin, wọ́n di òfin fún ara wọn. Irú àwọn wọnyi fihàn pé a ti kọ iṣẹ́ ti Òfin sinu ọkàn wọn. Ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ ninu wọn: àwọn èrò oríṣìíríṣìí tí ó wà ninu wọn yóo máa dá wọn láre tabi kí ó máa dá wọn lẹ́bi, ní ọjọ́ tí Ọlọrun yóo rán Jesu láti ṣe ìdájọ́ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo tí ó wà ninu eniyan gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí mò ń waasu. Ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní Juu, o gbójú lé Òfin, o wá ń fọ́nnu pé o mọ Ọlọrun. O mọ ohun tí Ọlọrun fẹ́. O mọ àwọn ohun tí ó dára jù nítorí a ti fi Òfin kọ́ ọ. O dá ara rẹ lójú bí ẹni tí ó jẹ́ amọ̀nà fún àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ninu òkùnkùn. O pe ara rẹ ní ẹni tí ó lè bá àwọn tí kò gbọ́n wí, olùkọ́ àwọn ọ̀dọ́, ẹni tí ó mọ àwọn nǹkan tí ó jẹ́ kókó ati òtítọ́ tí ó wà ninu Òfin. Ìwọ tí ò ń kọ́ ẹlòmíràn, ṣé o kò ní kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ò ń waasu pé kí eniyan má jalè, ṣé ìwọ náà kì í jalè? Ìwọ tí o sọ pé kí eniyan má ṣe àgbèrè, ṣé ìwọ náà kì í ṣe àgbèrè? Ìwọ tí o kórìíra oriṣa, ṣé o kì í ja ilé ìbọ̀rìṣà lólè? Ìwọ tí ò ń fọ́nnu pé o mọ Òfin, ṣé o kì í mú ẹ̀gàn bá Ọlọrun nípa rírú Òfin? Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Orúkọ Ọlọrun di ohun ìṣáátá láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu nítorí yín.” Ilà tí o kọ ní anfaani, bí o bá ń pa Òfin mọ́. Ṣugbọn tí o bá rú Òfin, bí àìkọlà ni ìkọlà rẹ rí. Ǹjẹ́ bí aláìkọlà bá ń pa àwọn ìlànà òdodo tí ó wà ninu Òfin mọ́, a kò ha ní ka àìkọlà rẹ̀ sí ìkọlà? Ẹni tí a bí ní aláìkọlà tí ó ń pa Òfin mọ́, ó mú ìtìjú bá ìwọ tí a kọ Òfin sílẹ̀ fún, tí o kọlà, ṣugbọn sibẹ tí o jẹ́ arúfin. Kì í ṣe nǹkan ti òde ara ni eniyan fi ń jẹ́ Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìkọlà kì í ṣe kí á fabẹ gé ara. Ṣugbọn láti jẹ́ Juu tòótọ́ jẹ́ ohun àtinúwá; ìkọlà jẹ́ nǹkan ti ọkàn. Nǹkan ti ẹ̀mí ni, kì í ṣe ti inú ìwé. Ìyìn irú ẹni bẹ́ẹ̀ wà lọ́dọ̀ Ọlọrun, kì í ṣe ọ̀dọ̀ eniyan.