Rom 13:11-14
Rom 13:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati eyi, bi ẹ ti mọ̀ akokò pe, o ti to wakati nisisiyi fun nyin lati ji loju orun: nitori nisisiyi ni igbala wa sunmọ etile jù igbati awa ti gbagbọ́ lọ. Oru bukọja tan, ilẹ si fẹrẹ mọ́: nitorina ẹ jẹ ki a bọ́ ara iṣẹ òkunkun silẹ, ki a si gbe ihamọra imọlẹ wọ̀. Jẹ ki a mã rìn ìrin titọ, bi li ọsán; kì iṣe ni iréde-oru ati ni imutipara, kì iṣe ni iwa-ẽri ati wọbia, kì iṣe ni ìja ati ilara. Ṣugbọn ẹ gbe Jesu Kristi Oluwa wọ̀, ki ẹ má si pèse fun ara, lati mã mu ifẹkufẹ rẹ̀ ṣẹ.
Rom 13:11-14 Yoruba Bible (YCE)
Ó yẹ kí ẹ mọ irú àkókò tí a wà yìí, kí ẹ tají lójú oorun. Nítorí àkókò ìgbàlà wa súnmọ́ tòsí ju ìgbà tí a kọ́kọ́ gbàgbọ́ lọ. Alẹ́ ti lẹ́ tipẹ́. Ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á pa iṣẹ́ òkùnkùn tì, kí á múra gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ogun ìmọ́lẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á máa rìn bí ó ti yẹ ní ọ̀sán, kí á má wà ninu àwùjọ aláriwo ati ọ̀mùtí, kí á má máa ṣe ìṣekúṣe, kí á má máa hu ìwà wọ̀bìà, kí á má máa ṣe aáwọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí á má máa jowú. Ṣugbọn ẹ gbé Oluwa Jesu Kristi wọ̀ bí ihamọra. Ẹ má jẹ́ kí á máa gbèrò láti ṣe àwọn ohun tí ara fẹ́.
Rom 13:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ. Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀. Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara. Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.