Rom 13

13
Ipò Àwọn Aláṣẹ Ìlú
1KI olukuluku ọkàn ki o foribalẹ fun awọn alaṣẹ ti o wà ni ipo giga. Nitori kò si aṣẹ kan, bikoṣe lati ọdọ Ọlọrun wá: awọn alaṣẹ ti o si wà, lati ọdọ Ọlọrun li a ti làna rẹ̀ wá.
2Nitorina ẹniti o ba tapá si aṣẹ, o tapá si ìlana Ọlọrun: awọn ẹniti o ba si ntapá, yio gbà ẹbi fun ara wọn.
3Nitori awọn ijoye kì iṣe ẹ̀ru si iṣẹ rere, bikoṣe si iṣẹ buburu. Njẹ iwọ ha fẹ ṣaibẹru aṣẹ wọn? ṣe eyi ti o dara, iwọ ó si gbà iyìn lati ọdọ rẹ̀:
4Nitori iranṣẹ Ọlọrun ni iṣe si ọ fun rere. Ṣugbọn bi iwọ ba nṣe buburu, bẹru; nitori kò gbé idà na lasan: nitori iranṣẹ Ọlọrun ni iṣe, olugbẹsan lati ṣiṣẹ ibinu lara ẹniti nṣe buburu.
5Nitorina ẹnyin kò gbọdọ ṣaima tẹriba, kì iṣe nitoriti ibinu nikan, ṣugbọn nitori ẹri-ọkàn pẹlu.
6Nitori idi eyi na li ẹ ṣe san owo-ode pẹlu: nitori iranṣẹ Ọlọrun ni nwọn eyiyi na ni nwọn mbojuto nigbagbogbo.
7Nitorina ẹ san ohun ti o tọ fun ẹni gbogbo: owo-ode fun ẹniti owo-ode iṣe tirẹ̀: owo-bode fun ẹniti owo-bode iṣe tirẹ̀; ẹ̀ru fun ẹniti ẹ̀ru iṣe tirẹ̀; ọlá fun ẹniti ọlá iṣe tirẹ̀.
Ìfẹ́ Láàrin Àwọn Onigbagbọ
8Ẹ máṣe jẹ ẹnikẹni ni gbese ohun kan, bikoṣepe ki a fẹran ọmọnikeji ẹni: nitori ẹniti o ba fẹran ọmọnikeji rẹ̀, o kó ofin já.
9Nitori eyi, Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga, Iwọ kò gbọdọ pania, Iwọ kò gbọdọ jale, Iwọ kò gbọdọ jẹri eke, Iwọ kò gbọdọ ṣojukòkoro; bi ofin miran ba si wà, a ko o pọ ninu ọ̀rọ yi pe, Fẹran ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.
10Ifẹ kì iṣe ohun buburu si ọmọnikeji rẹ̀: nitorina ifẹ li akója ofin.
Ọjọ́ Oluwa Fẹ́rẹ̀ Dé
11Ati eyi, bi ẹ ti mọ̀ akokò pe, o ti to wakati nisisiyi fun nyin lati ji loju orun: nitori nisisiyi ni igbala wa sunmọ etile jù igbati awa ti gbagbọ́ lọ.
12Oru bukọja tan, ilẹ si fẹrẹ mọ́: nitorina ẹ jẹ ki a bọ́ ara iṣẹ òkunkun silẹ, ki a si gbe ihamọra imọlẹ wọ̀.
13Jẹ ki a mã rìn ìrin titọ, bi li ọsán; kì iṣe ni iréde-oru ati ni imutipara, kì iṣe ni iwa-ẽri ati wọbia, kì iṣe ni ìja ati ilara.
14Ṣugbọn ẹ gbe Jesu Kristi Oluwa wọ̀, ki ẹ má si pèse fun ara, lati mã mu ifẹkufẹ rẹ̀ ṣẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Rom 13: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa