Rom 1:25-32

Rom 1:25-32 Yoruba Bible (YCE)

Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọrun pada sí irọ́. Wọ́n ń bọ nǹkan tí Ọlọrun dá, wọ́n ń tẹríba fún wọn, dípò èyí tí wọn ìbá fi máa sin ẹni tí ó dá wọn, ẹni tí ìyìn yẹ fún títí lae. Amin. Nítorí náà, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí ó ti eniyan lójú. Àwọn obinrin wọn ń bá ara wọn ṣe ohun tí kò bójú mu. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọkunrin wọn. Dípò tí ọkunrin ìbá máa fi bá obinrin lòpọ̀, ọkunrin ati ọkunrin ni wọ́n ń dìde sí ara wọn ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn. Ọkunrin ń bá ọkunrin ṣe ohun ìtìjú, wọ́n wá ń jèrè ìṣekúṣe wọn. Nígbà tí wọn kò ka ìmọ̀ Ọlọrun sí, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ọkàn wọn tí kò tọ́, kí wọn máa ṣe àwọn ohun tí kò yẹ. Wọ́n wá kún fún oríṣìíríṣìí ìwà burúkú: ojúkòkòrò, ìkà, owú jíjẹ, ìpànìyàn, ìrúkèrúdò, ẹ̀tàn, inú burúkú. Olófòófó ni wọ́n, ati abanijẹ́; wọn kò sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun. Wọ́n jẹ́ aláfojúdi, onigbeeraga, afọ́nnu, ati elérò burúkú; wọn kì í gbọ́ràn sí òbí lẹ́nu; wọn kò sì ní ẹ̀rí ọkàn. Aláìṣeégbẹ́kẹ̀lé ni wọ́n, aláìnífẹ̀ẹ́, ati aláìláàánú. Wọ́n mọ ìlànà ti Ọlọrun; wọ́n mọ̀ pé ikú ni ó tọ́ sí àwọn tí wọn bá ń hu irú ìwà wọnyi; sibẹ kì í ṣe pé wọ́n ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ nìkan, wọ́n tún ń kan sáárá sí àwọn tí ń hùwà bẹ́ẹ̀.

Rom 1:25-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín. Nítorí èyí yìí ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́: nítorí àwọn obìnrin wọn tilẹ̀ ń yí ìṣẹ̀dá ìbáṣepọ̀ tí ó tọ̀nà, sí èyí tí kò tọ̀nà. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí. Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe: Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ a fi-ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-banijẹ́. Asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, akórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgbọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n mọ ìlànà Ọlọ́run pé, ẹni tí ó bá ṣe irú nǹkan wọ̀nyí yẹ sí ikú, wọn kò ní inú dídùn sí àwọn nǹkan wọ̀nyí nìkan ṣùgbọ́n wọ́n ní inú dídùn sí àwọn tí ń ṣe wọ́n.