Rom 1

1
Ìkíni
1PAULU, iranṣẹ Jesu Kristi, ti a pè lati jẹ aposteli, ti a yà sọ̀tọ fun ihinrere Ọlọrun,
2(Ti o ti ṣe ileri tẹlẹ rí ninu iwe-mimọ́, lati ọwọ awọn woli rẹ̀),
3Niti Ọmọ rẹ̀, ti a bí lati inu irú-ọmọ Dafidi nipa ti ara,
4Ẹniti a pinnu rẹ̀ lati jẹ pẹlu agbara Ọmọ Ọlọrun, gẹgẹ bi Ẹmí iwa mimọ́, nipa ajinde kuro ninu okú, ani Jesu Kristi Oluwa wa:
5Lati ọdọ ẹniti awa ri ore-ọfẹ ati iṣẹ aposteli gbà, fun igbọràn igbagbọ́ lãrin gbogbo orilẹ-ède, nitori orukọ rẹ̀:
6Larin awọn ẹniti ẹnyin pẹlu ti a pè lati jẹ ti Jesu Kristi:
7Si gbogbo ẹniti o wà ni Romu, olufẹ Ọlọrun, ti a pè lati jẹ mimọ́: Ore-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa wá, ati Jesu Kristi Oluwa.
Paulu Ṣàníyàn láti Lọ sí Romu
8Mo kọ́ dupẹ na lọwọ Ọlọrun mi nipasẹ Jesu Kristi nitori gbogbo nyin, nitoripe a nròhin igbagbọ́ nyin yi gbogbo aiye ká.
9Ọlọrun sá li ẹlẹri mi, ẹniti emi nfi ẹmi mi sìn ninu ihinrere Ọmọ rẹ̀, biotiṣepe li aisimi li emi nranti nyin nigbagbogbo ninu adura mi;
10Emi mbẹ̀bẹ, bi lọna-kọna leke gbogbo rẹ̀, ki a le ṣe ọ̀na mi ni ire nipa ifẹ Ọlọrun, lati tọ̀ nyin wá.
11Nitoriti emi nfẹ gidigidi lati ri nyin, ki emi ki o le fun nyin li ẹ̀bun ẹmi diẹ, ki a le fi ẹsẹ nyin mulẹ;
12Eyini ni, ki a le jùmọ ni itunu ninu nyin nipa igbagbọ́ awa mejeji, ti nyin ati ti emi.
13Ará, emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀ pe, nigba-pupọ li emi npinnu rẹ̀ lati tọ̀ nyin wá (ṣugbọn o di ẹtì fun mi di isisiyi,) ki emi ki o le ni eso diẹ ninu nyin pẹlu, gẹgẹ bi lãrin awọn Keferi iyokù.
14Mo di ajigbese awọn Hellene ati awọn alaigbede; awọn ọlọ́gbọn ati awọn alaigbọn.
15Tobẹ̃ bi o ti wà ni ipá mi, mo mura tan lati wasu ihinrere fun ẹnyin ara Romu pẹlu.
Agbára Ìyìn Rere
16Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu.
17Nitori ninu rẹ̀ li ododo Ọlọrun hàn lati igbagbọ́ de igbagbọ́: gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ṣugbọn olododo yio wà nipa igbagbọ́.
Gbogbo Aráyé Jẹ̀bi Ẹ̀ṣẹ̀
18Nitori a fi ibinu Ọlọrun hàn lati ọrun wá si gbogbo aiwa-bi-Ọlọrun ati aiṣododo enia, awọn ẹniti o fi aiṣododo tẹ otitọ mọ́lẹ̀:
19Nitori ohun ti ã le mọ̀ niti Ọlọrun o farahàn ninu wọn; nitori Ọlọrun ti fi i hàn fun wọn.
20Nitori ohun rẹ̀ ti o farasin lati igba dida aiye a ri wọn gbangba, a nfi òye ohun ti a da mọ̀ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ̀ aiyeraiye, ki nwọn ki o le wà li airiwi:
21Nitori igbati nwọn mọ̀ Ọlọrun, nwọn kò yìn i logo bi Ọlọrun, bẹ̃ni nwọn kò si dupẹ; ṣugbọn èro ọkàn wọn di asán, a si mu ọkàn òmúgọ wọn ṣókunkun.
22Nwọn npè ara wọn li ọlọ́gbọn, nwọn di aṣiwere,
23Nwọn si pa ogo Ọlọrun ti kì idibajẹ dà, si aworan ere enia ti idibajẹ, ati ti ẹiyẹ, ati ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin, ati ohun ti nrakò.
24Nitorina li Ọlọrun ṣe fi wọn silẹ ninu ifẹkufẹ ọkàn wọn si ìwa-ẽri lati ṣe aibọ̀wọ fun ara wọn larin ara wọn:
25Awọn ẹniti o yi otitọ Ọlọrun pada si eke, nwọn si bọ, nwọn si sìn ẹda jù Ẹlẹda lọ, ẹniti iṣe olubukun titi lai. Amin.
26Nitori eyiyi li Ọlọrun ṣe fi wọn fun ifẹ iwakiwa: nitori awọn obinrin wọn tilẹ yi ilo ẹda pada si eyi ti o lodi si ẹda:
27Gẹgẹ bẹ̃ li awọn ọkunrin pẹlu, nwọn a mã fi ilò obinrin nipa ti ẹda silẹ, nwọn a mã ni ifẹkufẹ gbigbona si ara wọn; ọkunrin mba ọkunrin ṣe eyi ti kò yẹ, nwọn si njẹ ère ìṣina wọn ninu ara wọn bi o ti yẹ si.
28Ati gẹgẹ bi nwọn ti kọ̀ lati ni ìro Ọlọrun ni ìmọ wọn, Ọlọrun fi wọn fun iyè rirà lati ṣe ohun ti kò tọ́:
29Nwọn kún fun aiṣododo gbogbo, àgbere, ìka, ojukòkoro, arankan; nwọn kún fun ilara, ipania, ija, itanjẹ, iwa-buburu; afi-ọrọ-kẹlẹ banijẹ,
30Asọrọ ẹni lẹhin, akorira Ọlọrun, alafojudi, agberaga, ahalẹ, alaroṣe ohun buburu, aṣaigbọran si obí,
31Alainiyè-ninu, ọ̀dalẹ, alainifẹ, agídi, alailãnu:
32Awọn ẹniti o mọ̀ ilana Ọlọrun pe, ẹniti o ba ṣe irú nkan wọnyi, o yẹ si ikú, nwọn kò ṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn nwọn ni inu didùn si awọn ti nṣe wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Rom 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa