Rom 1:20-25
Rom 1:20-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ohun rẹ̀ ti o farasin lati igba dida aiye a ri wọn gbangba, a nfi òye ohun ti a da mọ̀ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ̀ aiyeraiye, ki nwọn ki o le wà li airiwi: Nitori igbati nwọn mọ̀ Ọlọrun, nwọn kò yìn i logo bi Ọlọrun, bẹ̃ni nwọn kò si dupẹ; ṣugbọn èro ọkàn wọn di asán, a si mu ọkàn òmúgọ wọn ṣókunkun. Nwọn npè ara wọn li ọlọ́gbọn, nwọn di aṣiwere, Nwọn si pa ogo Ọlọrun ti kì idibajẹ dà, si aworan ere enia ti idibajẹ, ati ti ẹiyẹ, ati ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin, ati ohun ti nrakò. Nitorina li Ọlọrun ṣe fi wọn silẹ ninu ifẹkufẹ ọkàn wọn si ìwa-ẽri lati ṣe aibọ̀wọ fun ara wọn larin ara wọn: Awọn ẹniti o yi otitọ Ọlọrun pada si eke, nwọn si bọ, nwọn si sìn ẹda jù Ẹlẹda lọ, ẹniti iṣe olubukun titi lai. Amin.
Rom 1:20-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí. Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá, wọ́n sì yí ògo Ọlọ́run tí kì í díbàjẹ́ sí àwọn àwòrán ère bí i ti ènìyàn tí í díbàjẹ́ àti ti ẹyẹ, àti ti ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin àti ti ẹranko afàyàfà. Nítorí náà Ọlọ́run fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun ìríra pẹ̀lú ara wọn èyí tí kò tọ́. Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọ́run sí èké, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ láti máa sin ẹ̀dá dípò ẹlẹ́dàá—ẹni tí ìyìn tọ́ sí láéláé. Àmín.
Rom 1:20-25 Yoruba Bible (YCE)
Láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ayé ni ìwà ati ìṣe Ọlọrun, tí a kò lè fi ojú rí ati agbára ayérayé rẹ̀, ti hàn gedegbe ninu àwọn ohun tí ó dá. Nítorí èyí, irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kò ní àwáwí. Wọ́n mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò júbà rẹ̀ bí Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo èrò wọn di asán, òye ọkàn wọn sì ṣókùnkùn. Wọ́n ń ṣe bí ẹni pé wọ́n gbọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ya òmùgọ̀. Wọ́n yí ògo Ọlọrun tí kò lè bàjẹ́ pada sí àwòrán ẹ̀dá tí yóo bàjẹ́; bíi àwòrán eniyan, ẹyẹ, ẹranko ati ejò. Nítorí náà Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ láti máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn. Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọrun pada sí irọ́. Wọ́n ń bọ nǹkan tí Ọlọrun dá, wọ́n ń tẹríba fún wọn, dípò èyí tí wọn ìbá fi máa sin ẹni tí ó dá wọn, ẹni tí ìyìn yẹ fún títí lae. Amin.