Rom 1:20-21
Rom 1:20-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ohun rẹ̀ ti o farasin lati igba dida aiye a ri wọn gbangba, a nfi òye ohun ti a da mọ̀ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ̀ aiyeraiye, ki nwọn ki o le wà li airiwi: Nitori igbati nwọn mọ̀ Ọlọrun, nwọn kò yìn i logo bi Ọlọrun, bẹ̃ni nwọn kò si dupẹ; ṣugbọn èro ọkàn wọn di asán, a si mu ọkàn òmúgọ wọn ṣókunkun.
Rom 1:20-21 Yoruba Bible (YCE)
Láti ìgbà tí Ọlọrun ti dá ayé ni ìwà ati ìṣe Ọlọrun, tí a kò lè fi ojú rí ati agbára ayérayé rẹ̀, ti hàn gedegbe ninu àwọn ohun tí ó dá. Nítorí èyí, irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kò ní àwáwí. Wọ́n mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò júbà rẹ̀ bí Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo èrò wọn di asán, òye ọkàn wọn sì ṣókùnkùn.
Rom 1:20-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀: bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí. Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn.