Rom 1:14-17
Rom 1:14-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo di ajigbese awọn Hellene ati awọn alaigbede; awọn ọlọ́gbọn ati awọn alaigbọn. Tobẹ̃ bi o ti wà ni ipá mi, mo mura tan lati wasu ihinrere fun ẹnyin ara Romu pẹlu. Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu. Nitori ninu rẹ̀ li ododo Ọlọrun hàn lati igbagbọ́ de igbagbọ́: gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ṣugbọn olododo yio wà nipa igbagbọ́.
Rom 1:14-17 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé ati àwọn Giriki tí wọ́n jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n, ati àwọn kògbédè tí kò mọ nǹkan, gbogbo wọn ni mo jẹ ní gbèsè. Ìdí rẹ̀ nìyí tí mo ṣe ń dàníyàn láti waasu ìyìn rere fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Romu náà. Ojú kò tì mí láti waasu ìyìn rere Jesu, nítorí ìyìn rere yìí ni agbára Ọlọrun, tí a fi ń gba gbogbo àwọn tí ó bá gbà á gbọ́ là. Ó kọ́kọ́ lo agbára yìí láàrin àwọn Juu, lẹ́yìn náà ó lò ó láàrin àwọn Giriki. Ninu ìyìn rere yìí ni a ti ń fi ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre hàn wá: nípa igbagbọ ni, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí igbagbọ ni ẹni tí a bá dá láre yóo fi yè.”
Rom 1:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Giriki àti sí àwọn aláìgbédè tí kì í ṣe Giriki, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aṣiwèrè. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Romu àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìhìnrere Ọlọ́run sí i yín. Èmi kò tijú ìhìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú. Nítorí nínú ìhìnrere ni òdodo Ọlọ́run ti farahàn, òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.”