Rom 1:1-7
Rom 1:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
PAULU, iranṣẹ Jesu Kristi, ti a pè lati jẹ aposteli, ti a yà sọ̀tọ fun ihinrere Ọlọrun, (Ti o ti ṣe ileri tẹlẹ rí ninu iwe-mimọ́, lati ọwọ awọn woli rẹ̀), Niti Ọmọ rẹ̀, ti a bí lati inu irú-ọmọ Dafidi nipa ti ara, Ẹniti a pinnu rẹ̀ lati jẹ pẹlu agbara Ọmọ Ọlọrun, gẹgẹ bi Ẹmí iwa mimọ́, nipa ajinde kuro ninu okú, ani Jesu Kristi Oluwa wa: Lati ọdọ ẹniti awa ri ore-ọfẹ ati iṣẹ aposteli gbà, fun igbọràn igbagbọ́ lãrin gbogbo orilẹ-ède, nitori orukọ rẹ̀: Larin awọn ẹniti ẹnyin pẹlu ti a pè lati jẹ ti Jesu Kristi: Si gbogbo ẹniti o wà ni Romu, olufẹ Ọlọrun, ti a pè lati jẹ mimọ́: Ore-ọfẹ si nyin ati alafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa wá, ati Jesu Kristi Oluwa.
Rom 1:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Èmi Paulu, iranṣẹ Kristi Jesu, ni mò ń kọ ìwé yìí. Ọlọrun pè mí, ó fi mí ṣe òjíṣẹ́, ó sì yà mí sọ́tọ̀ láti máa waasu ìyìn rere rẹ̀. Bí a bá wo inú Ìwé Mímọ́, a óo rí i pé àwọn wolii ti kéde ìyìn rere náà tẹ́lẹ̀ rí. Ìyìn rere Ọmọ Ọlọrun tí a bí ninu ìdílé Dafidi nípa ti ara. Ọmọ rẹ̀ yìí ni Ọlọrun fi agbára Ẹ̀mí Mímọ́ yàn nígbà tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú. Òun náà ni Jesu Kristi Oluwa wa, nípa ẹni tí a ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà, tí a sì gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní orúkọ rẹ̀, pé kí gbogbo eniyan lè gba Jesu gbọ́, kí wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Ẹ̀yin tí mò ń kọ ìwé yìí sí náà wà lára àwọn tí Jesu Kristi pè. Gbogbo ẹ̀yin àyànfẹ́ Ọlọrun tí ẹ wà ní Romu, ẹ̀yin tí a pè láti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi, kí ó wà pẹlu yín.
Rom 1:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Paulu, ìránṣẹ́ Jesu Kristi, ẹni tí a ti pè láti jẹ́ aposteli, tí a sì ti yà sọ́tọ̀ láti wàásù ìhìnrere Ọlọ́run, ìhìnrere tí ó ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ rí láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ nínú ìwé Mímọ́. Ní ti Ọmọ rẹ̀, ẹni tí a bí láti inú irú-ọmọ Dafidi nípa ti ara, ẹni tí a pinnu rẹ̀ láti jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run nínú agbára gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ìwà mímọ́, nípa àjíǹde kúrò nínú òkú, àní Jesu Kristi Olúwa wa. Láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwa rí oore-ọ̀fẹ́ àti jíjẹ́ aposteli gbà, fún ìgbọ́ràn ìgbàgbọ́ láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, nítorí orúkọ rẹ̀. Ẹ̀yin pẹ̀lú si wa lára àwọn tí a pè sọ́dọ̀ Jesu Kristi. Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Romu tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́