Ifi 22:6-11
Ifi 22:6-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wi fun mi pe, ododo ati otitọ li ọ̀rọ wọnyi: Oluwa Ọlọrun ẹmi awọn woli li o si rán angẹli rẹ̀ lati fi ohun ti kò le ṣaiṣẹ kánkán hàn awọn iranṣẹ rẹ̀. Kiyesi i, emi mbọ̀ kánkán: ibukún ni fun ẹniti npa ọ̀rọ isọtẹlẹ inu iwe yi mọ́. Emi Johanu li ẹniti o gbọ́ ti o si ri nkan wọnyi. Nigbati mo si gbọ́ ti mo si ri, mo wolẹ lati foribalẹ niwaju ẹsẹ angẹli na, ti o fi nkan wọnyi hàn mi. Nigbana li o wi fun mi pe, Wo o, máṣe bẹ̃: iranṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ li emi, ati ti awọn arakunrin rẹ woli, ati ti awọn ti npa ọ̀rọ inu iwe yi mọ́: foribalẹ fun Ọlọrun. O si wi fun mi pe, Máṣe fi èdidi di ọ̀rọ isọtẹlẹ ti inu iwe yi: nitori ìgba kù si dẹ̀dẹ̀. Ẹniti iṣe alaiṣõtọ, ki o mã ṣe alaiṣõtọ nṣó: ati ẹniti iṣe ẹlẹgbin, ki o mã ṣe ẹlẹgbin nṣó: ati ẹniti iṣe olododo, ki o mã ṣe olododo nṣó: ati ẹniti iṣe mimọ́, ki o mã ṣe mimọ́ nṣó.
Ifi 22:6-11 Yoruba Bible (YCE)
Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Oluwa Ọlọrun tí ó mí sinu àwọn wolii rẹ̀ ni ó rán angẹli rẹ̀ pé kí ó fi àwọn ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn iranṣẹ rẹ̀.” “Mò ń bọ̀ kíákíá. Ẹni tí ó bá pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́ ṣe oríire.” Èmi Johanu ni mo gbọ́ nǹkan wọnyi, tí mo sì rí wọn. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí wọn, mo dojúbolẹ̀ níwájú angẹli tí ó fi wọ́n hàn mí. Ṣugbọn ó sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi náà ati ti àwọn wolii, arakunrin rẹ, ati ti àwọn tí wọ́n ti pa àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí mọ́. Ọlọrun ni kí o júbà.” Ó tún sọ fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí nítorí àkókò tí wọn yóo ṣẹ súnmọ́ tòsí. Ẹni tí ó bá ń hùwà burúkú, kí ó máa hùwà burúkú rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣe ohun èérí, kí ó máa ṣe ohun èérí rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó bá ń hùwà rere, kí ó máa hùwà rere rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun, kí ó máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun bọ̀.”
Ifi 22:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì wí fún mi pé, “Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran angẹli rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.” “Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́!” Èmi, Johanu, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ angẹli náà, tí o fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi, Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́: foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!” Ó sì wí fún mi pé, “má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí: nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹni tí ń ṣe aláìṣòótọ́, kí ó máa ṣe aláìṣòótọ́ nì só: àti ẹni tí ń ṣe ẹlẹ́gbin, kí ó máa ṣe ẹ̀gbin nì só: àti ẹni tí ń ṣe olódodo, kí ó máa ṣe òdodo nì só: Àti ẹni tí ń ṣe mímọ́, kí ó máa ṣe mímọ́ nì só.”