ÌFIHÀN 22
22
1Ó wá fi odò omi ìyè hàn mí, tí ó mọ́ gaara bíi dígí. Ó ń ti ibi ìtẹ́ Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ṣàn wá.#Isi 47:1; Sak 14:8 2Ó gba ààrin títì ìlú náà. Igi ìyè kan wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ òsì odò náà. Igi ìyè yìí ń so èso mejila, ọ̀kan ní oṣooṣù. Ewé igi náà wà fún ìwòsàn àwọn orílẹ̀-èdè.#Jẹn 2:9; Isi 47:12 3Kò ní sí ègún mọ́.#Sak 14:11 (Jẹn 3:17)
Ìtẹ́ Ọlọrun ati ti Ọ̀dọ́ Aguntan yóo wà níbẹ̀. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ yóo máa sìn ín. 4Wọn óo rí i lojukooju, orúkọ rẹ̀ yóo sì wà níwájú wọn. 5Kò ní sí òru mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní nílò ìmọ́lẹ̀ àtùpà tabi ìmọ́lẹ̀ oòrùn, nítorí Oluwa Ọlọrun wọn ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún wọn. Wọn yóo sì máa jọba lae ati laelae.#a Ais 60:19; b Dan 7:18
Dídé Kristi
6Ó tún sọ fún mi pé, “Òdodo ati òtítọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Oluwa Ọlọrun tí ó mí sinu àwọn wolii rẹ̀ ni ó rán angẹli rẹ̀ pé kí ó fi àwọn ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn iranṣẹ rẹ̀.”
7“Mò ń bọ̀ kíákíá. Ẹni tí ó bá pa àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́ ṣe oríire.”
8Èmi Johanu ni mo gbọ́ nǹkan wọnyi, tí mo sì rí wọn. Nígbà tí mo gbọ́, tí mo sì rí wọn, mo dojúbolẹ̀ níwájú angẹli tí ó fi wọ́n hàn mí. 9Ṣugbọn ó sọ fún mi pé, “Èèwọ̀! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Iranṣẹ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi náà ati ti àwọn wolii, arakunrin rẹ, ati ti àwọn tí wọ́n ti pa àwọn ọ̀rọ̀ ìwé yìí mọ́. Ọlọrun ni kí o júbà.” 10Ó tún sọ fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí nítorí àkókò tí wọn yóo ṣẹ súnmọ́ tòsí. Ẹni tí ó bá ń hùwà burúkú, kí ó máa hùwà burúkú rẹ̀ bọ̀. 11Ẹni tí ó bá ń ṣe ohun èérí, kí ó máa ṣe ohun èérí rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó bá ń hùwà rere, kí ó máa hùwà rere rẹ̀ bọ̀. Ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun, kí ó máa ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún Ọlọrun bọ̀.”#Dan 12:10
12“Mò ń bọ̀ ní kíá. Èrè mi sì wà lọ́wọ́ mi, tí n óo fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí.#a Ais 40:10; 62:11 b O. Daf 28:4; Ais 40:10; Jer 17:10 13Èmi ni Alfa ati Omega, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.”#a Ifi 1:8; b Ais 44:6; 48:12; Ifi 1:17; 2:8
14Àwọn tí wọ́n bá fọ aṣọ wọn ṣe oríire. Wọn óo ní àṣẹ láti dé ibi igi ìyè, wọn óo sì gba ẹnu ọ̀nà wọ inú ìlú mímọ́ náà.#Jẹn 2:9; 3:22 15Lóde ni àwọn ajá yóo wà ati àwọn oṣó ati àwọn àgbèrè, ati àwọn apànìyàn ati àwọn abọ̀rìṣà ati àwọn tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe èké.
16“Èmi Jesu ni mo rán angẹli mi láti jíṣẹ́ gbogbo nǹkan wọnyi fún ẹ̀yin ìjọ. Èmi gan-an ni gbòǹgbò ati ọmọ Dafidi. Èmi ni ìràwọ̀ òwúrọ̀.”#Ais 11:1,10
17Ẹ̀mí ati Iyawo ń wí pé, “Máa bọ̀!”
Ẹni tí ó gbọ́ níláti sọ pé, “Máa bọ̀.”
Ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ kí ó wá, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mu omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.#Ais 55:1
18Mò ń kìlọ̀ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá fi nǹkankan kún un, Ọlọrun yóo fi kún àwọn ìyà rẹ̀ tí a ti kọ sinu ìwé yìí. 19Bí ẹnikẹ́ni bá mú nǹkankan kúrò ninu ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí, Ọlọrun yóo mú ìpín rẹ̀ kúrò lára igi ìyè ati kúrò ninu ìlú mímọ́ náà, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé yìí.#Diut 4:2; 12:32
20Ẹni tí ó jẹ́rìí sí nǹkan wọnyi sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, tètè máa bọ̀. Amin! Máa bọ̀, Oluwa Jesu.”
21Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu gbogbo yín.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌFIHÀN 22: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010