Ifi 22:18-19
Ifi 22:18-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi njẹri fun olukuluku ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ isọtẹlẹ iwe yi pe, Bi ẹnikẹni ba fi kún wọn, Ọlọrun yio fi kún awọn iyọnu ti a kọ sinu iwe yi fun u. Bi ẹnikẹni ba si mu kuro ninu ọ̀rọ iwe isọtẹlẹ yi, Ọlọrun yio si mu ipa tirẹ̀ kuro ninu iwe ìye, ati kuro ninu ilu mimọ́ nì, ati kuro ninu awọn ohun ti a kọ sinu iwe yi.
Ifi 22:18-19 Yoruba Bible (YCE)
Mò ń kìlọ̀ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá fi nǹkankan kún un, Ọlọrun yóo fi kún àwọn ìyà rẹ̀ tí a ti kọ sinu ìwé yìí. Bí ẹnikẹ́ni bá mú nǹkankan kúrò ninu ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ìwé yìí, Ọlọrun yóo mú ìpín rẹ̀ kúrò lára igi ìyè ati kúrò ninu ìlú mímọ́ náà, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ninu ìwé yìí.
Ifi 22:18-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkù ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fi kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un. Bí ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò sì mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúrò nínú ìlú mímọ́ náà, àti kúrò nínú àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí.