Ifi 22:13-15
Ifi 22:13-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi ni Alfa ati Omega, ẹni iṣaju ati ẹni ikẹhin, ipilẹṣẹ̀ ati opin. Ibukún ni fun awọn ti nfọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o le ni anfani lati wá si ibi igi ìye na, ati ki nwọn ki o le gba awọn ẹnubode wọ inu ilu na. Nitori li ode ni awọn ajá gbé wà, ati awọn oṣó, ati awọn àgbere, ati awọn apania, ati awọn abọriṣa, ati olukuluku ẹniti o fẹran eke ti o si nhuwa eke.

Ifi 22:13-15 Yoruba Bible (YCE)
Èmi ni Alfa ati Omega, ẹni àkọ́kọ́ ati ẹni ìkẹyìn, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.” Àwọn tí wọ́n bá fọ aṣọ wọn ṣe oríire. Wọn óo ní àṣẹ láti dé ibi igi ìyè, wọn óo sì gba ẹnu ọ̀nà wọ inú ìlú mímọ́ náà. Lóde ni àwọn ajá yóo wà ati àwọn oṣó ati àwọn àgbèrè, ati àwọn apànìyàn ati àwọn abọ̀rìṣà ati àwọn tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe èké.
Ifi 22:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ni Alfa àti Omega, ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. “Ìbùkún ni fún àwọn ti ń fọ aṣọ wọn, kí wọ́n lè ni ẹ̀tọ́ láti wá sí ibi igi ìyè náà, àti kí wọ́n lè gbà àwọn ẹnu ibodè wọ inú ìlú náà. Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké.