O. Daf 95:7-11
O. Daf 95:7-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori on li Ọlọrun wa; awa si li enia papa rẹ̀, ati agutan ọwọ rẹ̀. Loni bi ẹnyin o ba gbọ́ ohùn rẹ̀, Ẹ má sé aiya nyin le, bi ti Meriba ati bi ọjọ na ni Massa, li aginju. Nigbati awọn baba nyin dan mi wò, ti nwọn wadi mi, ti nwọn si ri iṣẹ mi. Ogoji-ọdun tọ̀tọ ni inu mi fi bajẹ si iran na, mo ni, Enia ti o ṣina li aiya ni nwọn, nwọn kò si mọ̀ ọ̀na mi: Awọn ẹniti mo si bura fun ni ibinu mi pe, nwọn ki yio wọ ibi isimi mi.
O. Daf 95:7-11 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí òun ni Ọlọrun wa, àwa ni eniyan rẹ̀, tí ó ń kó jẹ̀ káàkiri, àwa ni agbo aguntan rẹ̀. Bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀ lónìí, ẹ má ṣe orí kunkun bí ẹ ti ṣe ní Meriba, ati bí ẹ ti ṣe ní ijọ́un ní Masa, ninu aṣálẹ̀ nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò, tí wọ́n dẹ mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti rí ohun tí mo ti ṣe rí. Fún ogoji ọdún gbáko ni ọ̀rọ̀ wọn fi sú mi, tí mo sọ pé, “Ọkàn àwọn eniyan wọnyi ti yapa, wọn kò sì bìkítà fún ìlànà mi.” Nítorí náà ni mo fi fi ibinu búra pé, wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.
O. Daf 95:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí òun ni Ọlọ́run wa àwa sì ni ènìyàn pápá rẹ̀, àti ọ̀wọ́ ẹran ni abẹ́ ìpamọ́ rẹ̀. Lónìí tí ìwọ bá gbọ́ ohùn rẹ̀, “Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ní Meriba, àti bí ẹ ti ṣe ní ọjọ́ náà ní Massa ní aginjù, Nígbà tí àwọn baba yín dán mi wò tí wọn wádìí mi, tí wọn sì rí iṣẹ́ mi Fún ogójì ọdún ni èmi fi bínú sí ìran náà; mo wí pé, ‘Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ọkàn wọn ṣáko lọ wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’ Nítorí náà ni mo kéde ìbúra nínú ìbínú mi ‘Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.’ ”