O. Daf 95

95
Orin Ìyìn
1ẸWÁ, ẹ jẹ ki a kọrin si Oluwa: ẹ jẹ ki a hó iho ayọ̀ si apata igbala wa.
2Ẹ jẹ ki a fi ọpẹ wá si iwaju rẹ̀, ki a si fi orin mimọ́ hó iho ayọ̀ si ọdọ rẹ̀.
3Nitori Oluwa, Ọlọrun ti o tobi ni, ati Ọba ti o tobi jù gbogbo oriṣa lọ,
4Ni ikawọ ẹniti ibi ọgbun ilẹ wà: giga awọn òke nla ni tirẹ̀ pẹlu.
5Tirẹ̀ li okun, on li o si dá a: ọwọ rẹ̀ li o si dá iyangbẹ ilẹ.
6Ẹ wá, ẹ jẹ ki a wolẹ, ki a tẹriba: ẹ jẹ ki a kunlẹ niwaju Oluwa, Ẹlẹda wa.
7Nitori on li Ọlọrun wa; awa si li enia papa rẹ̀, ati agutan ọwọ rẹ̀. Loni bi ẹnyin o ba gbọ́ ohùn rẹ̀,
Ọlọrun Bá Àwọn Eniyan Rẹ̀ sọ̀rọ̀
8Ẹ má sé aiya nyin le, bi ti Meriba ati bi ọjọ na ni Massa, li aginju.
9Nigbati awọn baba nyin dan mi wò, ti nwọn wadi mi, ti nwọn si ri iṣẹ mi.
10Ogoji-ọdun tọ̀tọ ni inu mi fi bajẹ si iran na, mo ni, Enia ti o ṣina li aiya ni nwọn, nwọn kò si mọ̀ ọ̀na mi:
11Awọn ẹniti mo si bura fun ni ibinu mi pe, nwọn ki yio wọ ibi isimi mi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 95: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa