O. Daf 90:1-17

O. Daf 90:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA, iwọ li o ti nṣe ibujoko wa lati irandiran. Ki a to bí awọn òke nla, ati ki iwọ ki o to dá ilẹ on aiye, ani lati aiye-raiye, iwọ li Ọlọrun. Iwọ sọ enia di ibajẹ; iwọ si wipe, Ẹ pada wá, ẹnyin ọmọ enia. Nitoripe igbati ẹgbẹrun ọdun ba kọja li oju rẹ, bi aná li o ri, ati bi igba iṣọ́ kan li oru. Iwọ kó wọn lọ bi ẹnipe ni ṣiṣan-omi; nwọn dabi orun; ni kutukutu nwọn dabi koriko ti o dagba soke. Ni Kutukutu o li àwọ lara, o si dàgba soke, li asalẹ a ké e lulẹ, o si rọ. Nitori awa di egbé nipa ibinu rẹ, ati nipa ibinu rẹ ara kò rọ̀ wa. Iwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ wa ka iwaju rẹ, ohun ìkọkọ wa mbẹ ninu imọlẹ iwaju rẹ. Nitori ọjọ wa gbogbo nyipo lọ ninu ibinu rẹ: awa nlo ọjọ wa bi alá ti a nrọ́. Adọrin ọdun ni iye ọjọ ọdun wa; bi o si ṣepe nipa ti agbara, bi nwọn ba to ọgọrin ọdun, agbara wọn lãla on ibinujẹ ni; nitori pe a kì o pẹ ke e kuro, awa a si fò lọ. Tali o mọ̀ agbara ibinu rẹ? gẹgẹ bi ẹ̀ru rẹ, bẹ̃ni ibinu rẹ. Bẹ̃ni ki iwọ ki o kọ́ wa lati ma ka iye ọjọ wa, ki awa ki o le fi ọkàn wa sipa ọgbọ́n. Pada, Oluwa, yio ti pẹ to? yi ọkàn pada nitori awọn ọmọ-ọdọ rẹ. Fi ãnu rẹ tẹ́ wa li ọrùn ni kutukutu; ki awa ki o le ma yọ̀, ati ki inu wa ki o le ma dùn li ọjọ wa gbogbo. Mu inu wa dùn bi iye ọjọ ti iwọ pọ́n wa loju, ati iye ọdun ti awa ti nri buburu. Jẹ ki iṣẹ rẹ ki o hàn si awọn ọmọ-ọ̀dọ rẹ, ati ogo rẹ si awọn ọmọ wọn. Jẹ ki ẹwà Oluwa Ọlọrun wa ki o wà lara wa: ki iwọ ki o si fi idi iṣẹ ọwọ wa mulẹ lara wa, bẹ̃ni iṣẹ ọwọ wa ni ki iwọ ki o fi idi rẹ̀ mulẹ.

O. Daf 90:1-17 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA, ìwọ ni o ti jẹ́ ibi ààbò wa láti ìrandíran. Kí o tó dá àwọn òkè, ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé, láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun. O sọ eniyan di erùpẹ̀ pada, o sì wí pé, “Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ eniyan.” Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹrun ọdún dàbí àná, tabi bí ìṣọ́ kan ní òru. Ìwọ a máa gbá ọmọ eniyan dànù; wọ́n dàbí àlá, bíi koríko tí ó tutù ní òwúrọ̀; ní òwúrọ̀ á máa gbilẹ̀, á sì máa jí pérépéré; ní ìrọ̀lẹ́ á sá, á sì rọ. Ibinu rẹ pa wá run; ìrúnú rẹ sì bò wá mọ́lẹ̀. O ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa kalẹ̀ ní iwájú rẹ; àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa sì hàn kedere ninu ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ. Nítorí ọjọ́ ayé wa ń kọjá lọ ninu ibinu rẹ; ayé wa sì ń dópin bí ẹni mí kanlẹ̀. Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa; pẹlu ipá a lè tó ọgọrin; sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu; kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ. Ta ló mọ agbára ibinu rẹ? Ta ló sì mọ̀ pé bí ẹ̀rù rẹ ti tó bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ rí? Nítorí náà kọ́ wa láti máa ka iye ọjọ́ orí wa, kí á lè kọ́gbọ́n. Yipada sí wa, OLUWA; yóo ti pẹ́ tó tí o óo máa bínú sí wa? Ṣàánú àwa iranṣẹ rẹ. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀, kí á lè máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Mú inú wa dùn fún iye ọjọ́ tí o ti fi pọ́n wa lójú, ati fún iye ọdún tí ojú wa ti fi rí ibi. Jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ, kí agbára rẹ tí ó lógo sì hàn sí àwọn ọmọ wọn. Jẹ́ kí ojurere OLUWA Ọlọrun wa wà lára wa, fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀, jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wa fi ìdí múlẹ̀.

O. Daf 90:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran. Kí a tó bí àwọn òkè ńlá àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé, láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run. Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀, wí pé “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.” Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú rẹ, bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru. Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú; wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀. Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù. A pa wá run nípa ìbínú rẹ nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá. Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ, àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ, Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ; àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́. Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá, bi ó sì ṣe pé nípa agbára tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún, agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni, nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò, àwa a sì fò lọ. Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ? Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ. Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára, kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n. Yípadà, OLúWA! Yóò ti pẹ́ tó? Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ. Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ, kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀ kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́. Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú, fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà. Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn. Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa; fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.