ORIN DAFIDI 90:1-17

ORIN DAFIDI 90:1-17 YCE

OLUWA, ìwọ ni o ti jẹ́ ibi ààbò wa láti ìrandíran. Kí o tó dá àwọn òkè, ati kí o tó dá ilẹ̀ ati ayé, láti ayérayé, ìwọ ni Ọlọrun. O sọ eniyan di erùpẹ̀ pada, o sì wí pé, “Ẹ yipada, ẹ̀yin ọmọ eniyan.” Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹrun ọdún dàbí àná, tabi bí ìṣọ́ kan ní òru. Ìwọ a máa gbá ọmọ eniyan dànù; wọ́n dàbí àlá, bíi koríko tí ó tutù ní òwúrọ̀; ní òwúrọ̀ á máa gbilẹ̀, á sì máa jí pérépéré; ní ìrọ̀lẹ́ á sá, á sì rọ. Ibinu rẹ pa wá run; ìrúnú rẹ sì bò wá mọ́lẹ̀. O ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa kalẹ̀ ní iwájú rẹ; àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ wa sì hàn kedere ninu ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ. Nítorí ọjọ́ ayé wa ń kọjá lọ ninu ibinu rẹ; ayé wa sì ń dópin bí ẹni mí kanlẹ̀. Aadọrin ọdún ni ọjọ́ ayé wa; pẹlu ipá a lè tó ọgọrin; sibẹ gbogbo rẹ̀ jẹ́ kìkì làálàá ati ìyọnu; kíá, ayé wa á ti dópin, ẹ̀mí wa á sì fò lọ. Ta ló mọ agbára ibinu rẹ? Ta ló sì mọ̀ pé bí ẹ̀rù rẹ ti tó bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ rí? Nítorí náà kọ́ wa láti máa ka iye ọjọ́ orí wa, kí á lè kọ́gbọ́n. Yipada sí wa, OLUWA; yóo ti pẹ́ tó tí o óo máa bínú sí wa? Ṣàánú àwa iranṣẹ rẹ. Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀, kí á lè máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Mú inú wa dùn fún iye ọjọ́ tí o ti fi pọ́n wa lójú, ati fún iye ọdún tí ojú wa ti fi rí ibi. Jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ, kí agbára rẹ tí ó lógo sì hàn sí àwọn ọmọ wọn. Jẹ́ kí ojurere OLUWA Ọlọrun wa wà lára wa, fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀, jẹ́ kí iṣẹ́ ọwọ́ wa fi ìdí múlẹ̀.