O. Daf 81:1-16

O. Daf 81:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

KỌRIN soke si Ọlọrun, ipa wa: ẹ ho iho ayọ̀ si Ọlọrun Jakobu. Ẹ mu orin mimọ́, ki ẹ si mu ìlu wa, duru didùn pẹlu ohun-elo orin mimọ́. Ẹ fun ipè li oṣù titún, ni ìgbà ti a lana silẹ, li ọjọ ajọ wa ti o ni ironu. Nitori eyi li aṣẹ fun Israeli, ati ofin Ọlọrun Jakobu. Eyi li o dasilẹ ni ẹrí fun Josefu, nigbati o là ilẹ Egipti ja; nibiti mo gbe gbọ́ ede ti kò ye mi. Mo gbé ejika rẹ̀ kuro ninu ẹrù: mo si gbà agbọn li ọwọ rẹ̀. Iwọ pè ninu ipọnju, emi si gbà ọ; emi da ọ lohùn nibi ìkọkọ ãra: emi ridi rẹ nibi omi ija. Ẹ gbọ́, ẹnyin enia mi, emi o si jẹri si ọ: Israeli, bi iwọ ba fetisi mi. Kì yio si ọlọrun miran ninu nyin; bẹ̃ni iwọ kì yio sìn ọlọrun àjeji. Emi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti jade wá: yà ẹ̀nu rẹ̀ gbòro, emi o si kún u. Ṣugbọn awọn enia mi kò fẹ igbọ́ ohùn mi; Israeli kò si fẹ ti emi. Bẹ̃ni mo fi wọn silẹ fun lile aiya wọn: nwọn si nrìn ninu ero ara wọn. Ibaṣepe awọn enia mi ti gbọ́ ti emi, ati ki Israeli ki o ma rìn nipa ọ̀na mi! Emi iba ti ṣẹ́ awọn ọta wọn lọgan, emi iba si ti yi ọwọ mi pada si awọn ọta wọn. Awọn akorira Oluwa iba ti fi ori wọn balẹ fun u; igba wọn iba si duro pẹ titi. Alikama daradara ni on iba ma fi bọ́ wọn pẹlu: ati oyin inu apata ni emi iba si ma fi tẹ́ ọ lọrun.

O. Daf 81:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ kọ orin sókè sí Ọlọrun, agbára wa; ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun Jakọbu. Ẹ dárin, ẹ lu samba, ẹ ta hapu dídùn ati lire. Ẹ fọn fèrè ní ọjọ́ oṣù titun, ati ní ọjọ́ oṣù tí a yà sọ́tọ̀, ati ní ọjọ́ àsè. Nítorí pé àṣẹ ni, fún àwọn ọmọ Israẹli, ìlànà sì ni, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Jakọbu. Ó pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Josẹfu, nígbà tí ó kọlu ilẹ̀ Ijipti. Mo gbọ́ ohùn kan tí n kò gbọ́ rí: tí ó wí pé, “Mo ti sọ àjàgà náà kalẹ̀ lọ́rùn rẹ; mo ti gba agbọ̀n ẹrù kúrò lọ́wọ́ rẹ. Ninu ìnira, o ké pè mí, mo sì gbà ọ́; mo dá ọ lóhùn ninu ìjì ààrá, níbi tí mo fara pamọ́ sí; mo sì dán ọ wò ninu omi odò Meriba. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo bá ń kìlọ̀ fun yín, àní kí ẹ fetí sílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli! Kò gbọdọ̀ sí ọlọrun àjèjì kan kan láàrin yín; ẹ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún oriṣa-koriṣa kan. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti. Ẹ ya ẹnu yín dáradára, n óo sì bọ yín ní àbọ́yó. “Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, Israẹli kò sì gba tèmi. Nítorí náà mo fi wọ́n sílẹ̀ sinu agídí ọkàn wọn, kí wọn máa ṣe ohun tó wù wọ́n. Àwọn eniyan mi ìbá jẹ́ gbọ́ tèmi, àní Israẹli ìbá jẹ́ máa rìn ní ọ̀nà mi! Kíákíá ni èmi ìbá kọjú ìjà sí àwọn ọ̀tá wọn, tí ǹ bá sì ṣẹgun wọn. Àwọn tí ó kórìíra OLUWA yóo fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba fún un, ìyà óo sì jẹ wọ́n títí lae. Ṣugbọn èmi ó máa fi ọkà tí ó dára jùlọ bọ yín, n óo sì fi oyin inú àpáta tẹ yín lọ́rùn.”

O. Daf 81:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu! Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá, tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́. Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun àní nígbà tí a yàn; ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú. Èyí ni àṣẹ fún Israẹli, àti òfin Ọlọ́run Jakọbu. Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já. Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa. Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín, a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀. Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là, mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá, mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela. “Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín, bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli. Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín; ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì. Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti. Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un. “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi; Israẹli kò ní tẹríba fún mi. Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn. “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi, Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn! Àwọn tí ó kórìíra OLúWA yóò tẹríba níwájú rẹ̀. Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”