O. Daf 80:1-7
O. Daf 80:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
FI eti si ni, Oluṣọ-agutan Israeli, iwọ ti o ndà Josefu bi ọwọ́-agutan; iwọ ti o joko lãrin awọn kerubu tàn imọlẹ jade. Niwaju Efraimu ati Benjamini ati Manasse rú ipa rẹ soke ki o si wá fun igbala wa. Tún wa yipada, Ọlọrun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là. Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, iwọ o ti binu pẹ to si adura awọn enia rẹ? Iwọ fi onjẹ omije bọ́ wọn; iwọ si fun wọn li omije mu li ọ̀pọlọpọ. Iwọ sọ wa di ijà fun awọn aladugbo wa: awọn ọta wa si nrẹrin ninu ara wọn. Tún wa yipada, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.
O. Daf 80:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli, Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran. Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́ níwájú Efuraimu ati Bẹnjamini ati Manase. Sọ agbára rẹ jí, kí o sì wá gbà wá là. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun; fi ojurere wò wá, kí á le gbà wá là. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa bínú sí adura àwọn eniyan rẹ? O ti fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ, o sì ti fún wọn ní omijé mu ní àmuyó. O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa; àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun; fi ojurere wò wá, kí á lè là.
O. Daf 80:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli; ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran; ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde Níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase. Ru agbára rẹ̀ sókè; wá fún ìgbàlà wa. Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run; jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí a bá à lè gbà wá là. OLúWA Ọlọ́run alágbára, ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ? Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá. Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára; jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa, kí a ba à lè gbà wá là.